Àṣẹ̀ṣẹ̀gbàgbọ́Àpẹrẹ
Ìmúdúró ìgbé ayé ìjọba Ọlọ́run
Àtúnbí ènìyàn sí inú ìgbàlà fara pẹ́ ìbí ọmọ tuntun sí ìyá rẹ̀. Bí ìyá ṣe ní ojúṣe láti tọ́jú ọmọ rẹ̀ nípa pípèsè mílìkì, ó nígbà gbọ́ tuntun tí a ti bí sí inú ìjọba Ọlọ́run ni à ń retí ìdagbà rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tuntun, onígbàgbọ́ yẹ "kó pòǹgbẹ mílìkì ti ẹ̀mí" ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè máa dàgbà nínú ìgbàlà wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni atọ́ka tó ń tọ́ sọ́nà àti ró igbe ayé tuntun nínú Krístì lágbára. Agbára ńlá àti ìyè ni a rí nínú kíka àti ṣíṣe àmúlò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí máa ń yọrí sí àyípadà àti ìsọdọ̀tun ọkàn ènìyàn.
Àdúrà jẹ́ ohun èlò pàtàkì mìíràn fún ìdàgbàsókè onígbàgbọ́. Ó jẹ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ríró onígbàgbọ́ lágbára, pípèsè ìdarí àti ọgbọ́n láti la ayé já. Àdúrà máa ń sọ ìbáṣepọ̀ láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn di ọ̀tun, ríran onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti wu Ọlọ́run.
Ìgbé ayé tuntun ti onígbàgbọ́ níí ṣe pẹ̀lú fífi ara mọ́ àṣà tuntun, ètò àlàkalẹ̀ àti ìgbàgbọ́. Ó jẹ́ dandan láti wà ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí ó jẹ́ onígbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ní gbogbo ìgbà, nítorí àwọn akẹgbẹ́ ti àtẹ̀yìnwá lè má ní òye tàbí fara mọ́ ìpinnu yìí.
Onígbàgbọ́ mi ọ̀wọ́n, ìhìn ni ó yẹ kí o wà - pẹ̀lú òmìnira nínú Krístì. Ríi dájú pé ó wà ní òmìnira o kò sí ní àjọṣe pọ̀ pẹ̀lú ohun àtijọ́ mọ́. Dàgbà nínú ìgbàlà rẹ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àdúrà, àti àwùjọ Krìstẹ́nì.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Jésù Krístì wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àtúnbí sínú ayé tuntun ni. Nítorí náà ó ṣe pàtàkì pé kí onígbàgbọ́ tuntun ní òye ìhùwàsí, àǹfààní àti àṣà ayé tuntun yìí.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/