Àṣẹ̀ṣẹ̀gbàgbọ́Àpẹrẹ

Àṣẹ̀ṣẹ̀gbàgbọ́

Ọjọ́ 1 nínú 3

Káàbọ̀ sínú ẹbí náà!

Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́ ni? Káàbọ́ sínú ẹbí náà!

Ó ṣe pàtàkì kí o mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ayé rẹ

A dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó jìyà ìpínyà àti ìhé kúrò ìdàpọ̀ nígbà tí Ádámù àkọ́kọ́ ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ràn wa ju kó fi wá sílẹ̀ fún ìbàjẹ́ gbogbo ìgbà. Ó ní ètò fún ìràpadà wa, ètò fún ìfẹ́ aláì ní dìí, ètò láti kó yọ; ẹ̀bùn ìgbàlà. Ó mú un ṣẹ nípa ríran ọmọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo láti kú fún wa. Jésù wá ní àwòrán ènìyàn ó sì gbé ní àìlẹ́ṣẹ̀. Ó dúró ní ipò wá, ó ru ẹṣẹ̀ wa bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní àìlẹ́ṣẹ̀ ó sì san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa tíi ṣe ikú orí igi àgbélébùú

Gbogbo ohun tí a nílò láti ṣe ni láti gbàgbọ́ kí a sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa àti Jésù Olúwa wa, fífi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sílẹ̀, a sì ní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Bí o bá ti ṣe èyí, nígbà náà dídàbí náà ti dá ọ padà.

Ẹ̀bùn ìgbàlà ti mú ìdáríjì wá fún oy. Ọlọ́run ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jìnnà sí ọ ó sì mú àìṣedéédé rẹ bí ẹni wí pé o kò ṣẹ̀ rí. Àtúnbí ni. O ti di àtúnbí! Ó ti darapọ̀ mọ ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Àṣẹ̀ṣẹ̀gbàgbọ́

Jésù Krístì wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àtúnbí sínú ayé tuntun ni. Nítorí náà ó ṣe pàtàkì pé kí onígbàgbọ́ tuntun ní òye ìhùwàsí, àǹfààní àti àṣà ayé tuntun yìí.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/