ÌDARÍÀpẹrẹ

ÌDARÍ

Ọjọ́ 3 nínú 3

RÍRÓ OLÓRÍ LÁGBÁRA

Ǹjẹ́ o ti jẹ oúnjẹ aládùn kan rí tí o sì ń fẹ́ láti jẹ sí i?

Kì í ṣe ìwọ nìkan nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó ti jẹ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ rí. ṣùgbọ́n ohun kan tí o gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ nip é ó ti la àwọn ìgbésẹ̀ kan kọjá bí i gígé, bíbọ̀, sísè, dídín abbl.

Bákan náà, àwọn ènìyàn kì í bọ́ sí iò olórí àfi bí Ọlọ́run bá ti sè wọ́n tí ó sì ti pèsè wọn sílẹ̀. Yàrá ìpèsè Ọlọ́run kì í ṣábà rọrùn ṣùgbọ́n àwọn oúnjẹ tí ó jẹ́ ayọrísí rẹ̀ dára púpọ̀.

Nígbà tí Ọlọ́run bá yan ènìyàn kan fún iṣẹ́ ìdarí, Ó máa mú un lọ sí ibùdó ìwàkùsà rl fún gígé, rírọ àti mímú ṣe rẹ́gí kí ó tó mú un jáde láti kọ ilé ńlá nínú ìjọba Rẹ̀.

Púpọ̀ àwọn olórí aláṣeyọrí nínú ìtàn ni wọ́n ti dé ibùdó ìwàkùsà tàbí yàrá ìpèsè ti Ọlọ́run. Ibẹ̀ ni ó ti máa ń gbé wọn ró pẹ̀lú agbára àti okun tí wọ́n nílò láti darí àwọn ènìyàn Rẹ̀.

Nítorí náà ó ṣe pàtàkì kí o má pàdánù àwọn ìgbésẹ̀ sísè àti gígé rẹ torí wọ́n máa jẹ́ kí o yẹ fún àwọn pèpéle ìdarí tí Ọlọ́run fẹ́ gbé ọ lé.

Joseefu jẹ́ ọkùnrin tí ó ní ọ̀pọ̀ ìrírí tí kò dára láti ìgbà èwe rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí ó ràn án lọ́wọ́ láti dé ipò olórí ní ilẹ̀ Ijibiti ni pé ó dúró nínú yàrá ìpèsè Ọlọ́run.

Dafidi, ọkùn ẹni bí ọkàn Ọlọ́run àti Ọba rere ní Isreli kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ìdojúkọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe tẹ̀síwájú lórí àkàbà lọ sí ipò ọba. Ó dojú kọ ọ̀kan nínú àwọn ìdanwò ńlá nígbà tí ó ní àǹfààní yálà láti pa lájorí ọ̀tá rẹ̀ (ọba Saulu) tàbí láti jẹ́ kó gbáyé. Lákòótán, kò kúrò ní ibùdó ìpesè Ọlọ́run. Kí Timoti tó di olórí nínú ìjọ, ó fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbésẹ̀ ìpèsè Ọlọ́run ní ọwọ́ Aposteli Paulu.

Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni Josua, Elisha tí ó ń da omi sí ọwọ́ Elijah, Aburaamu Baba, Mose…kí a kàn dárúkọ díẹ̀.

Máṣe sá fún ibùdó ìpèsè Ọlọ́run, dúró kí o sì jẹ́ kó fi ọ́ ṣe olórí tí ó yẹ kí o jẹ́.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

ÌDARÍ

Ìdarí jẹ́ ọ̀kan láti àwọn ìkànnì tí Ọlọ́run máa ń lò láti pèsè àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbésí-ayé àti iṣẹ̀-ńlá ti ìjọba rẹ̀. Àwọn èrèdí máa ń já gaara sí i, àwọn ìrìn-àjò máa dán mọ́nrán sí i láyé pẹ̀lú ìdarí tó tọ̀nà. Nítorí náà, Ọlọ́run ń mọ̀ọ́mọ̀ pe, ó sì ń fi agbára fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n máa mú ìpè ńlá yìí sẹ.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/