ÌDARÍÀpẹrẹ

ÌDARÍ

Ọjọ́ 1 nínú 3

ÌDARÍ PẸ̀LÚ ÌWÒYE ỌLỌ́RUN

Ọ̀kan nínú ìfẹ́ Ènìyàn tí ó ga jù ni láti wà lókè, kí ó máa jọba lórí àwọn nǹkan àti ènìyàn. Ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí jíjọba dípò kí wọ́n jọba lé e lórí.

Gbogbo ènìyàn ni ó fẹ́ kí wọ́n rí òun, bọ̀wọ̀ fún òun, àti pé kí òun di ‘’olóri ohun gbogbo’’

Ìfẹ́-inú yìí nìkan ni ó máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi tipátipá sọra wọn di olórí ti wọ́n sì ti fi ṣòfò dànù.

Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti ní òye gidi lórí ohun tí ṣíṣe adarí jẹ́ àti bí Ọlọ́run ṣe rí i.

Àwọn kókó-ọ̀rọ̀ méjì wọ̀nyí yẹ ni àkíyèsí:

1. Ìpè ni Ṣíṣe Ìdarí. Ọlọ́run máa ń pe àwọn ènìyàn sínú iṣẹ́ ìdarí, ó máa ń ka wọn ó sì máa ń fún wọn ní pore-ọ̀fẹ́ fún un.

Nítorí náà, ẹni tí Ọlọ́run pè tí ó kọ́ tí ó sì ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló lè darí dáadáa.

Àwọn ẹni bí I Mose, Aroni, Josua, Elisha, Dafidi, Paulu, àti àwọn Aposteli méjìlá, àti àwọn yòókù kò lo ipá fi ara wọn sípò adarí ṣùgbọ́n ńṣe ni Ọlọ́run yàn wọ́n.

"kò sì sí ẹni tí ó gba ọlá fún ara rẹ̀, bíkòṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aroni."

Heberu 5:4

2. Jíjẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ ọ̀nà sí dídi adarí. Matiu 20:25-28, Maku 10:44.

Jesu Kristi ṣípayá èyí nígbà tí ìfẹ́ láti darí dìdelẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó jẹ́ kí àwọn aposteli rẹ̀ mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ olórí láàrin wọn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ ìránṣẹ́.

Olórí gbọ́dọ̀ wá láti sìn dípò kí wọ́n sìn ín. Ó jẹ́ kó jẹ́ iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn tí a pè é pé kó darí. Jésù ṣe àfihàn àpẹẹrẹ ìdarí-ajẹmọ́-òjíṣẹ́ yìí nípa pípèsè àìní àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ti ẹ̀mí, ìṣúná àti ara. Ó tilẹ̀ tún ní láti fọ ẹsẹ̀ wọn ní àsìjò kan, èyí tí í ṣe ìṣe ìrẹ̀lẹ̀ fún olórí ní àsìkò Tirl. Olórí tó pé ló jẹ́!

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

ÌDARÍ

Ìdarí jẹ́ ọ̀kan láti àwọn ìkànnì tí Ọlọ́run máa ń lò láti pèsè àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbésí-ayé àti iṣẹ̀-ńlá ti ìjọba rẹ̀. Àwọn èrèdí máa ń já gaara sí i, àwọn ìrìn-àjò máa dán mọ́nrán sí i láyé pẹ̀lú ìdarí tó tọ̀nà. Nítorí náà, Ọlọ́run ń mọ̀ọ́mọ̀ pe, ó sì ń fi agbára fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n máa mú ìpè ńlá yìí sẹ.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/