ÈRÈDÍ Ìfojú-ìhìnrere wo ìwé JeremiahÀpẹrẹ

ÈRÈDÍ  Ìfojú-ìhìnrere wo ìwé Jeremiah

Ọjọ́ 3 nínú 3

Gbígbé Ìgbésíayé Èrèdí Ọlọ́run ní Ojoojúmọ́

Ìwé Efesu ṣàlàyé pé Ọlọ́run dá wa láti jẹ́ iṣẹ́-ọwọ́ rẹ̀. Ó mọ̀ọ́mọ̀ dá wa láti lè lò wá. Ọlọ́run dá wa kí á lè jẹ́ ohun-èlò alágbára fún ìjagun tàbí gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.

Lákọ̀ọ́kọ́, a kò yẹ ni ẹni ìgbàlà, ìṣubú ènìyàn nínú ìwé Gẹnesisi ti yà wá nípa sí Ọlọ́run ná. Èyí fa ìyàpa láàrin ènìyàn àti Ọlọ́run. Nítorí náà, ènìyàn nílò láti kọ́kọ́ ní ìmúpadàbọ̀sípò pẹ̀lú Ọlọ́run, kí ó tó dù láti gbé ìgbésí-ayé mímú èrèdí rẹ̀ ṣẹ. A di ẹni ìgbàlà nípasẹ̀ Oore-ọ̀fẹ́ a sì dá wa padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìbáṣepọ̀ tó kùnà láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn ni ohun àkọ́kọ́ tí a dá padà, èyí darí wa lọ sínú àǹfààní ìgbésí-ayé tí Ọlọ́run ti ṣètò fún wa. Kíyèsi pé bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, yóò nira láti gbé ìgbésí-ayé èrèdí Ọlọ́run fún wa bí a kò bá ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀.

Efesu 2 ẹsẹ 10 tẹ̀síwájú láti sọ pé Ọlọ́run dá wa láti ṣe iṣẹ́ rere. Èyí ni àpapọ̀ èrèdí ìṣẹ̀dá wa. A dá wa láti gbé ìgbésí-ayé tí ó fi ògo fún Ọlọ́run. Ìfihàn 4:11 ṣe àfihàn pé gbogbo wa ni a dá fún ìfẹ́-inú Ọlọ́run. Bákan náà, Matiu 5 ẹsẹ 16 ṣe ìtẹnumọ́ lórí kókó pé kí á tan ìmọ́lẹ̀ wa, kí á lè rí iṣẹ́ rere wa àti pé gbogbo ògo jẹ́ ti Ọlọ́run. Ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní í gbé ayé lọ́gán tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí Ọlọ́run fún ayé rẹ̀.

Ìgbésí-ayé wa gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ yẹ kí ó ní èròǹgbà àti wù ú àti gbígbé ayé ní ìbámu pẹ̀lú èrèdí ìwàláàyè wa. Ó máa ba Ọlọ́run lọ́kàn jẹ́ lọ́gán tí a bá yàn láti gbé ìgbésí-ayé wa bíi pé a ṣètò rẹ̀ tàbí dá a fún ara wa. Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé a kò dá ayé yìí fún ra wa, a jẹ́ pé ọgbọ́n ni ó jẹ́ láti gbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ètò àti èrèdí ìpìlẹ̀ rẹ̀ fún wa. Èyí ni ó mú ayọ̀ àti ìdùnnú wá fún Ọlọ́run. Ọ̀nà yìí ni ó máa ń ṣe é logo.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

ÈRÈDÍ  Ìfojú-ìhìnrere wo ìwé Jeremiah

Gbogbo olùpèsè-ọjà ló ní èrèdí fún pípèsè ọjà kọ̀ọ̀kan. Ọlọrun dá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ètò àti ìlànà pàtàkì kan. Èrèdí ìgbélé-ayé ni kí á rí i dájú pé a gbé ìgbésí ayé wa láti jẹ́ kí èrèdí yìí wá sí ìmúṣẹ. Ẹkọ yìí dù láti wa àwàjinlẹ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/