ÈRÈDÍ Ìfojú-ìhìnrere wo ìwé JeremiahÀpẹrẹ
Ṣíṣe Àwárí Èrèdí Ara-ẹni nínú Ètò Ọlọ́run
Ìpèdè kan wà pé “Bí èrèdí ohun kan kò bá di mímọ̀, àṣìlò jẹ́ kòṣeémánìí.” Èrèdí kì í ṣe àwọn ìṣe, èrèdí kì í ṣe ìlépa-ayé, kì í ṣe ohun tí ò ń ṣe ló sọ èrèdí rẹ. Èrèdí máa ń dáhùn ìbéèrè ‘‘kín ni ìdí?’’ Kín ni ìdí tí o fi fẹ́ ṣe é? Fún kín ni ni o fi ń ṣe é? Bí ènìyàn kò bá jókòó láti ṣe àwárí èrèdí rẹ̀, a jẹ́ pé sàtánì yóò ba irú àyànmọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́.
Nínú ìwé Jeremiah 29:11-13, a rí bí Ọlọ́run ṣe sọ ìdánilójú ètò rẹ̀. Ó pilẹ̀ ń sọ pé òún mọ̀ ètò tí òún ní; ó mọ èrèdí tí òún ní lọ́kàn fún ènìyàn. Àwọn ètò wọ̀nyí jẹ́ ètò rere. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Jeremiah, àwọn ètò wọ̀nyí ní í ṣe pllú kí á ní ìgbẹ̀yìn rere. Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ènìyàn ní èrèdí àti ètò fún ìwàláàyè wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn. ìbéèrè tó kà láti bèèrè ni KÍN NI? Bí èrèdi àti ètò Ọlọ́run bá wà fún ìwàláàyè wa, kín gan-an ni èrèdí yìí àti pé báwo ni a ṣe ń ṣe àwàrí wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé Jeremiah 29: 11-13 ṣe sọ, a rí i pé òpónà láti ṣe àwárí èrèdí àti láti mọ àwọn ètò Ọlọ́run fún wa ni kíké pe Ọlọ́run, gbígbàdúrà sí Ọlọ́run àti wíwá ojú rẹ̀. ọ̀nà yìí à ń gbà láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ àti pé Òun pẹ̀lú á fi ara wa hàn fún wa, ó tún máa fi èrèdí àti àwọn ètò rẹ̀ hàn fún wa. Báwo tún ni o ṣe lè mọ ètò tí olùpèsè ọjà ní fún ọjà jù pé kí á bá olùpèsè náà sọ̀rọ̀ kí o lè ba à mọ ìfẹ́-inú àti ọkàntàbí èrò tí ó wà lẹ́yìn ìpèsè ọjà náà. Ọlọ́run ni olùpèsè ti wa àwa sì ni ọjà rẹ̀, láti ṣe àwárí èrèdí rẹ̀ fún ìṣẹ̀dá wa, a jẹ́ pé ó rọrùn ó sì pé láti sọ wíwá a di lájorí ohun àmúṣe. à ń wá ojú rẹ̀ nínú àdúrà, a sì ń dù láti gbọ́ràn sí I lẹ́nu, ní gbogbo ìgbà tí ó bá fi àṣẹ síta. A tún lè sa ipá sí i láti wo inú wa fún àwọn agbára àdámọ́ tí ó fi sínú wa. Ní ọ̀nà yìí ni à ń gbà láti ṣe àwárí ìdí tí a fi ṣẹ̀dá wa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo olùpèsè-ọjà ló ní èrèdí fún pípèsè ọjà kọ̀ọ̀kan. Ọlọrun dá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ètò àti ìlànà pàtàkì kan. Èrèdí ìgbélé-ayé ni kí á rí i dájú pé a gbé ìgbésí ayé wa láti jẹ́ kí èrèdí yìí wá sí ìmúṣẹ. Ẹkọ yìí dù láti wa àwàjinlẹ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/