Ríràn nínú Èrò Ọlọ́runÀpẹrẹ
![Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F50474%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Lílo Àwọn Òkúta Rẹ
Nígbà tí mo jẹ́ ọmọdékùnrin, bàbá mi ra rọ́bà fún ṣíṣe ọdẹ ẹyẹ. Kò wúlò àfi bí o bá ní ìmọ̀ọ́ṣe àti ìrírí láti lò ó. Mo nìfẹ̀ẹ́ rọ́bà bàbá mi ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé n kò lè lò ó. N kò tíì kọ́ ara mi láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Dafidi náà ni irinṣẹ́ tí ó fara pẹ́ rọ́bà náà, ṣùgbọ́n kò bẹ̀rẹ̀ sí ní í lò okùn àti òkúta rẹ̀ ní ọjọ́ tí ó dojú kọ Goliath. Ó ti ń lò wọ́n fún ìgbà pípẹ́, tí ó ń mú ìmọ̀ọ́ṣe rẹ̀ dàgbà tí ó sì ń ka ara rẹ̀ kí ó lè baà ṣààbò fún àwọn àgùtàn bàbá rẹ̀.
Ó dùn ún gbọ́ láti kíyèsí pé a fún Dafidi ní aṣọ ìjà àti àṣíborí Saulu ṣùgbọ́n ó kọ̀ ọ́. Wọ́n ti tóbi jù, wọ́n wúwo jù. Wọn kò bá ti sọ ọ́ di aláìlágbára sí Goliath. Ó yé e pé Ọlọ́run ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ láti lo kànnàkànnà rẹ̀, ó sì jà pẹ̀lú èyí.
Ní Yunifásítì, mo nífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí ṣíṣe sinimá ìhìnrere. Mo tilẹ̀ fẹ́ àwọn irinṣẹ́ tó dára jù ní gbogbo ọ̀nà láti mú àlá yìí ṣẹ. Mo sọ fún bàbá mi pé mo fẹ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-fíìmù ní New York. Wọ́n sọ fún mi pé àwọn kò ní owó fún ìyẹn. Wọ́n rán mí létí pé ìdí tí ṣíṣe fíìmù fi yẹ kó máa wù mí ni láti bùkún àwọn ènìyàn nipa tẹ̀mí, kì í ṣe láti ṣe àfihàn àwọn ọgbọ́n mi, wọ́n wá gbà mí nímọ̀ràn láti kọ́ ara mi pẹ̀lú àwọn irinṣẹ́ tí mo ní lọ́wọ́. Gbogbo ohun tí mo ní lọ́wọ́ mi ni fóònù ìjọun kan. Mo ní kí Ọlọ́run kí ó kọ́ mi mo sì tètè mọ̀ pé Ẹ̀mí Mímọ́ ni olùka tó ga jùlọ tí a lè lérò. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ní lo fóònù mi láti ya àwọn fíìmù kékèké. Mo máa ń fi wọ́n sórí YouTube, wọ́n sì máa ń bùkún ọ̀pọ̀ ènìyàn. N kò dúró níbí. Mo tún ń ṣe sinimá sí i pẹ̀lú àwọn irinṣẹ́ òpè títí tí mo fi dáńtọ́ nínú ìlò wọn.
Ìlànà yìí jẹyọ nínú ìgbésí-ayé Dafidi. Kò mọ bí a ṣe ń lo àwọn idà àti ohun èlò ìjagun. Àwọn kànnàkànnà àti òkúta òpè rẹ̀ ti mọ́ ọn lára, ó sì ti dáńtọ́ nínú ìlò wọn.
Ó dára láti bẹ̀rẹ̀ ní kékeré bí a ṣe ń rìn nínú èrèdí Ọlọ́run fún ayé wa. Ọlọ́run ló ṣètò ìgbésẹ̀ ìdàgbà. Aginjù ti fi ìgbà kan jẹ́ igi kan ṣoṣo rí. Igi kan ti fi ìgbà kan jẹ́ hóró kan ṣoṣo. Ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń lá àlá dídi aginjù, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti orí hóró.Máṣe kánjú nínú ìgbésẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ. Máṣe kánjú láti lo idà nígbà tí Ọlọ́run sì ń kọ́ ẹ láti pẹ̀lú òkúta. Dafidi fi ọgbọ́n kọ ìhámọ́ra àti idà Saulu, dípò bẹ́ẹ̀, ó yan òkúta márùn-ún. Ó ti lè dàbí wèrè sí àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dàbí pé ó yé Dafidi pékì í ṣe gbogbo àǹfààní tàbí ìlẹ̀kùn tó ṣí ló wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Dafidi tún ní òye ìlànà ìdàgbàsókè. Ó mọ̀ pé kò tíì tó àsìkò fún idà – ìyẹn máa wá tó bá yá. Dípò bẹ́ẹ̀ ó yan ohun tí ó bá ìpéle ìmúrasílẹ̀ rẹ̀ mu: òkúta.
Àwọn òkúta Dafidi lè jẹ́ ohun ìjà àìlajú, ṣùgbọ́n àyọrísí wọn ní ògo nítorí pé ó ṣe àmúlò àwọn ohun èlò ní ọwọ́ rẹ̀. Ọlọ́run ń pè ọ́ láti ṣe bákan náà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F50474%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/