Ríràn nínú Èrò Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ọjọ́ 6 nínú 6

Ṣíṣe Ààbò Èrèdí Rẹ

Ó lọ́ pẹ̀lú àìsọ pé sàtánì kò fẹ́ kí o rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó máa ṣe ohunkóhun láti ba àyànmọ́ rẹ jẹ́. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti mọ bí o ṣe lè dáàbò bo èrèdí rẹ.

Dafidi dé láti ibi tó ti ṣẹ́gun Goliath sí ìyìn gbogbo ara Israeli – púpọ̀ rẹ̀ sí ìbànújẹ́ Saulu – ó sì bẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún ewu àti ìjà, èyí tí owú Saulu koná mọ́. Saulu pinnu láti ba èrèdí Daafidi jẹ́. ọmọ Saulu àti ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Dafidi, Jonataani, ki Dafidi nílọ̀ èrò Saulu láti pa á, Dafidi sì sá lọ. gẹ́gẹ́ bí olùgbé èrèdí Ọlọ́run ká, wà á nílò láti sá fún àwọn tó tako tàbí tí wọ́n fẹ́ ba àyànmọ́ rẹ jẹ́. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní òye ibi tí Ọlọ́run ti mú ọ wá àti ibi tí ó ń mú ọ lọ.

Ó lè tilẹ̀ nílò láti sá lọ sí inú irúfẹ̀ aginjù kan, bí Dafidi ti ṣe, nítorí pé Ọlọ́run fẹ́ kọ́ ọ ó sì fẹ́ tún ọ ṣe nípasẹ̀ mímú ọ kúrò ní ibùdó ìrọ̀rùn rẹ, tí ó sì ń sí ojú rẹ sí àwọn ìdojúkọ tó le. Èyí kì í ṣe láti ba èrèdí rẹ jẹ́ ṣùgbọ́n láti tún un ṣe. Wúrà máa ń la iná kọjá kí ó tó di pé ògo tòótọ́ rẹ̀ yóò tàn. Bákan náà, kí Ọlọ́run tó fi ọ́ hàn fún ayé, ó lè gbà ọ́ láàyè láti la iná kọjá. A dúpẹ́ pé Ó ṣe ìlérí láti wà pẹ̀lú rẹ àti láti dáàbò bò ọ́ nígbà tí o bá ń la iná àti ìkúnmi kọjá.

Láti dáàbò bo èrèdí Ọlọ́run nínú ayé rẹ, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni kíka àti dídúró ti òótọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ fún Dafidi, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ rẹ àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà rẹ. Pinnu ní ọkàn rẹ láti máṣe gbàgbọ́ nínú àwọn irọ́ ṣàtánì. Ohun tí ayé ń sọ nipa rẹ kò sọ ohun tí o jẹ́ tàbí ibi tí Ọlọ́run ń mú ọ lọ. Ọ̀nà tí ó dájú jù láti dààbò bo èrèdí rẹ ni láti gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ ohun tí Bàbá re Ọ̀run ti sọ nipa rẹ nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kì í sì ṣe ohun tí ìkànnì tọ́rọ́fọ́kálé ‘social media’ sọ nipa rẹ).

Lẹ́ẹ̀kejì, kọ́ ìjọ̀wọ́ ara-ẹni àti ìgbọràn sí ìtọ́ni. O nílò àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti lọ sáájú rẹ nínú ìrìn-àjò ayé.

Lẹ́ẹ̀kẹta, wà nílẹ̀ fún ìsìn. Bí o bá tóbi jù láti sìn, a jẹ́ pé ó kéré jù láti jẹ́ olórí. Gbogbo àwọn ènìyàn ńlá ló ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ìránṣẹ́. Kódà Dafidi sin ọba Israẹli ní àsìkò kan, tí ó sì di ọba fúnrarẹ̀ lẹ́yìn-ò-rẹyìn. Bí àlá rẹ bá jẹ́ láti di olórin ńlá, wá ẹ̀ka orin nínú ilé ìjọsìn rẹ̀ kí o sì máa sìn níbẹ̀, kódà ní àwọn ọ̀nà tí ó kéré jù.

Lẹ́ẹ̀kẹrin, jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ síbẹ̀. Ọlọ́run máa ń tako agbéraga ṣùgbọ́n ó máa ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀. Nígbà tí a bá gbẹ́kẹ̀lé E pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, ó máa ń gbé wa ga nígbà tí àsìkò bá tó.

Ìmọ̀lẹ̀ rẹ yóò tàn títí dé àwọn òpin ayé gẹ́gẹ́ bí o ṣe ń fi ayọ̀ rìn nínú èrèdí Ọlọ́run!

Nípa Ìpèsè yìí

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/