Ìjọsìn fún Ọlọ́runÀpẹrẹ

Worshipping God

Ọjọ́ 3 nínú 6

Ayọ̀ tí ó wà nínú Àìṣe Ohunkóhun

Ìpele ìjọsìn tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ sí wà, ọ̀kan nínú èyí tí a kò lè ṣẹ àfihàn rẹ́ fún ara wa jáde ní ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe ti ẹnu—ní ibi tí a kò tí lè ṣẹ ohunkóhun. Ìjọsìn tí o ga jù lọ àti èyí tí o ní agbára jù lọ ma ń wáyé ní ìgbà tí a kò lè ṣe ohunkóhun bí kò ṣe pé kí a kún fún ìyàlẹ́nu, ní ìgbà tí a ba sọ wà dì aláìlólùrànlọ́wọ́ àti aláìní ohùn pẹ̀lú ìyàlẹ́nu àti ọpẹ́, ní ìgbà tí a kàn jókòó l'áti wo Ọlọ́run bí ó ṣe n ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

Ǹjẹ́ o ti wà nínú ipò kàn tí o kò lè sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohunkóhun? Ẹnìkan ṣe ohun ìyanu ńlá, ṣùgbọ́n o kò lè ṣe ohunkóhun bí kò ṣe pé o kún fun ọpẹ́? Bóyá ẹni náà lọ, ó sì wù ọ́ pé kí o rí wọn láti sọ bí o ṣe mọ rírì ohun tí wọ́n ṣe. O wà lè bà ọ́ nínú jẹ́, o tún wà lè já kí ayọ rẹ dín kù nítorí pé kò sí ànfààní latí fi ọpẹ́ rẹ hàn. Ní orí ìpele àbùdá, gbogbo ìgbà ní a ǹ máa lérò pé a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun kan.

Èmi kò sọ pé a kò ní imọlara nǹkan kàn, ṣùgbọ́n kí a máa ṣe nǹkan kàn. Aísáyà sọ pé, èyí ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti gbé, ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ kí a máa gbé. Ó jẹ́ ayọ̀ ńlá tí o ga jù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ wá di aláìlólùrànlọ́wọ́—bí ẹni pé a kàn dúró síbẹ̀ tí ẹnu wa sì ṣí sílẹ̀—Ọlọ́run rí bí nǹkan ṣe rí l'ára ​​wa ó sì mọ̀ pé a mọ rírì oore rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worshipping God

Ibi kíkà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń fún wa ní ìṣírí nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run ní gbogbo agbọn ayé wa, yíó sì tún ru àwọn òǹkàwé sókè láti d'arí ọkàn wọn sí ìbájọṣepọ̀ won pẹ̀lú Krístì. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí dá lé orí ìwé R. T. Kendall Worshipping God (Sínsin Ọlọ́run). (R. T. Kendall jẹ́ olùṣó-àgùntàn ilé-ìjọsìn Westminster ní ìlú London, England, fún bíi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.)

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ R. T. Kendall àti Charisma House fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò: http://bit.ly/kendallkindle