Ìjọsìn fún Ọlọ́runÀpẹrẹ

Àdúrà Tí Ẹ̀mí Mímọ́
Arthur Blessitt, olùṣọ-àgùntàn tí ó ní ókìkí lágbàáyé, sọ nípa ìjọ kan tí wọn pinnu láti pàdé ní ọ̀sán Àbámẹ́ta kan láti gbàdúrà fún ìsọjí. Ó tó bíi ogójì ọkùnrin tí wọ́n wá, wọ́n jókòó ní olóbìrípo, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà.
Ṣùgbọ́n kò jọ pé wọ́n wà ní iwájú Ọlọ́run.
Ní àkókò yẹn, Arthur wo ojú fèrèsé, ó sì ṣàkíyèsí ilé oúnjẹ kan ní òdìkejì ọ̀pópónà. Ǹǹkan kan sọ sí í nínú pé kí ó dìde kí ó lọ síbẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó dúró ní ẹnu ọ̀nà, ó ní,, "Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni níbí fẹ́ gba ìgbàlà?"
Obìnrin adìgbàró kan sọ pé, "mo fẹ́."
Nítorí náà, ó ṣe àlàyé ìhìnrere fún un, Ó sì mú un tọ Olúwa wá.
Ó wá béèrè bóyá ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìjọ ní òdìkejì òpópónà ti bá a sọ̀rọ̀ nípa Jésù Krístì rí tàbí pè é wá sí ṣọ́ọ̀ṣì rí.
Ó ní, "Kò sí, kò sí ẹnìkan."
Síbẹ̀ àwọn ènìyàn yìí kan náà ń gbàdúrà fún ìsọjí.
Máṣe dá Ẹ̀mímímọ́ lẹ́kun nípa ríronú pé ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ̀ dáadáa, tí ó sì rọrùn fún ọ láti gbà ni ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ kí o gbà máa jọ́sìn. Àwọn ogójì ọkùnrin wọ̀nyìí ni wọ́n ní láti kúrò nínú ipò kíkú wọn. Ìjọsìn àti àdúrà lábẹ́ ìdarí Ẹ̀mí túmọ̀ sí pé kí á tẹ̀lé ìtọ́ni Ẹ̀mí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ibi kíkà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń fún wa ní ìṣírí nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run ní gbogbo agbọn ayé wa, yíó sì tún ru àwọn òǹkàwé sókè láti d'arí ọkàn wọn sí ìbájọṣepọ̀ won pẹ̀lú Krístì. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí dá lé orí ìwé R. T. Kendall Worshipping God (Sínsin Ọlọ́run). (R. T. Kendall jẹ́ olùṣó-àgùntàn ilé-ìjọsìn Westminster ní ìlú London, England, fún bíi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.)
More