Mo Yọ̀ǹda: Ìwé-Ìfọkànsìn Asínilórì Láti Ọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀nÀpẹrẹ
JÉSÙ WA NÍ HÌN
“Ó sọ Fún un pé, ‘Olúwa, MO ṣe tán láti bá Ọ lọ sínú túbú àti láti kú fún Ọ pẹ̀lú. ’”—LÚÙKÙ 22:33
Ni ìgbà kan, ni ìgbé ayé Pétérù, ó ṣe ìpinnu tí ó lágbára láti tẹ̀ lé Jésù. Ó ti lẹ̀ sọ pé òun yíò bá lọ sínú túbú àti láti kú Fún. Pétérù sọ òtítọ́ inú rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí àdánwò àti ìdojúkọ de ó kùnà! Ṣùgbọ́n Jésù ti gbàdúrà fún Pétérù bẹ́ẹ̀ ni kò dẹ́kun lórí rẹ̀.
Ǹjẹ́ àwa náà tí kùnà bí? Ǹjẹ́ a ti sẹ̀ Olùgbàlà wa bí, fà sẹhin, àti pé a kùnà pátápátá? Mú ara rẹ lọ́kàn lè. Tẹjú mọ Jésù. Ó ṣì wà nibẹ. Bẹni Ó nifẹ wà síbẹ̀. Ó ti gbàdúrà fún wa, àti lẹhin gbogbo ìjákulẹ̀ wa, Ó ṣé tán láti fà wá sókè, nù omijé ojú wa nù, àti kí Ó wo ìpòrúùrúù ọkàn wa sàn.
A lè tẹ síwájú láti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹni tí ó ńpa àwọn òfin àti ìlérí tí a ṣe fún Jésù mọ́. Ibikíbi tí o wu ki a wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ọ̀gbun inú túbú, irú ipò kí pò tí a bá bá ara wa, Jésù wá nibẹ pẹ̀lú wá. A lè ní ìgboyà láti sọ Fún wípé, "Mo ṣe tán, Olúwa, láti tẹ̀ lé Ọ lọ sínú túbú àti láti kú pẹ̀lú Rẹ̀"
—Javier
ÀDÚRÀ: Ó ṣe, Olúwa, bí a tilẹ̀ ni ìjákulẹ̀, Ó kó sọ ìrètí nù lórí wa. Àmín
IDAGBASOKE Bọtini: Ọjọ_3 Ọjọ́ _3Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bíbelì jẹ́ ìwé ìràpadà, òmìnira, àti ìrètí. Nínú àwọn ojú-ìwé rẹ̀ ni orírúirú ẹ̀dá ènìyàn, akínkanjú—àwọn oníròbìnùjẹ́-ọkàn l'ọ́kùnrin l'óbìnrin tí wọn ń wá ọ̀nà àbáyọ. Ní ọ̀nà kan tàbí òmínràn, wọ́n dàbìi àwọn àbọ̀dé elẹ́wọ̀n àná tàbí àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ tí wọ́n kọ àwọn ìwé-ìfọkànsìn tí o fẹ́ kà báyìí. A ní èrò pé àwọn ohùn ìjọ làti inú àhámọ́ yìí yíó jẹ́ ìgbaniníyànjú àti ìwúrí fún ọ. Kí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn dá àwa náà s'ílẹ̀.
More