Mo Yọ̀ǹda: Ìwé-Ìfọkànsìn Asínilórì Láti Ọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀nÀpẹrẹ
ỌLỌ́RUN NÍFÈ̩Ẹ́ MÍ
“Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi sì fi ìyè àìnípẹ̀kun fún wọn, wọn kì yóò sì ṣègbé láé, kò sì sí ẹnìkan tí yóò já wọn gbà a kúrò ní ọwọ́ mi.” —JÒHÁNÙ 10:27-28
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Kristẹni ni mí, àmọ́ nígbà tó yá mo kúrò nínú òtítọ́. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni mo ti wà nínú ìṣòro àti nínú ìdààmú, mo mọ̀ nínú ọkàn mi pé mo nílò Olúwa gan-an, àmọ́ mo ń bá a jà nítorí pé mo bẹ̀rù Rẹ̀. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ kan tó rọrùn gan-an rán mi létí pé Ọlọ́run ń fi tìfẹ́tìfẹ́ pè mí padà sínú agbo rẹ̀. Mi ò sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi fún àwọn ọmọ mi nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n. Nígbàkigbà tí mo bá pè wọ́n tàbí tí mo bá kọ̀wé sí wọn, ńṣe ni mo máa ń "lọ síbì kan", tí gbogbo nǹkan sì máa ń "bá a lọ dáadáa". Àmọ́ nígbà tó yá, obìnrin Kristẹni kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi àtàtà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n sọ fún mi pé kí n sọ òtítọ́ fún àwọn ọmọ mi.
Mo sọ fún wọn, mo sì fi ìdààmú dúró fún oṣù méjì kí wọ́n tó dá mi lóhùn. Níkẹyìn, mo gba ìbùkún ńlá kan - lẹ́tà àkọ́kọ́ látọ̀dọ̀ ọmọbìnrin mi.Ó fi àwọn lẹ́tà ńlá kọ ọ́ sára ìwé náà pé, "JỌWỌ KỌ̀WÉ SÍ WA LÀÍPẸ́ " àti pé, "MÁMÁ, MO MÁA FẸ́RÀN RẸ TÍTÍ LÁÉ".
Ọ̀rọ̀ ọmọbìnrin mi ṣí ojú mi sí òtítọ́ ńlá kan: Olúwa nífẹ̀ẹ́ mi nígbà gbogbo. Mo máa ń gbàdúrà pé kí n lè jẹ́ olóòótọ́ sí i kí n sì di ohunkóhun tó bá fẹ́ kí n jẹ́.
—Nina
ÁDÙRÁ:Olúwa, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tí o fẹ́ fún mi láti ìsinsìnyí lọ, lójoojúmọ́. Ẹ ṣeun fún sùúrù yín. Ran mi lọ́wọ́ láti máa ní sùúrù fún àwọn ẹlòmíràn. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bíbelì jẹ́ ìwé ìràpadà, òmìnira, àti ìrètí. Nínú àwọn ojú-ìwé rẹ̀ ni orírúirú ẹ̀dá ènìyàn, akínkanjú—àwọn oníròbìnùjẹ́-ọkàn l'ọ́kùnrin l'óbìnrin tí wọn ń wá ọ̀nà àbáyọ. Ní ọ̀nà kan tàbí òmínràn, wọ́n dàbìi àwọn àbọ̀dé elẹ́wọ̀n àná tàbí àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ tí wọ́n kọ àwọn ìwé-ìfọkànsìn tí o fẹ́ kà báyìí. A ní èrò pé àwọn ohùn ìjọ làti inú àhámọ́ yìí yíó jẹ́ ìgbaniníyànjú àti ìwúrí fún ọ. Kí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn dá àwa náà s'ílẹ̀.
More