Ìyípadà Láti Ṣẹ́pá Àwọn Ìdààmú ỌkànÀpẹrẹ

A U-Turn From Emotional Issues

Ọjọ́ 3 nínú 3

Ọ̀kan lára àwọn ipa tí ìmọ̀lára ní lórí àwọn ènìyàn lóde òní ni a mọ̀ sí gbígbáralé ẹlòmíràn ju bó ti yẹ lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn wà tí a lè fi ṣe àpèjúwe irú ìbáṣepọ̀ yí tí ó bá wà láàárín èèyàn mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ—àwọn ọ̀rọ̀ yí lè jẹ́ títẹ́ àwọn ènìyàn lọ́rùn àti ìfẹ́sódì àwọn òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ ṣe àgbéyèwò gbígbáralé ènìyàn.

Gbígbáralé ènìyàn jẹ́ ọ̀nà àbáyọ (èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ipá ìmọ̀lára) tí máa ran ènìyàn lọ́wọ́ láti kojú—àmọ́ lọ́nà tí kò tọ́—àwọn ǹkan tó kùdíẹ̀-kááàtó nínú ayé ẹnítọ̀ún. Bóyá kò tilẹ̀ sí iyì omonìyàn tàbí ṣe ní ẹnítọ̀ún ní èrò ìkọ̀sílẹ̀. Láì fi àwọn ǹkan wọ̀nyí ṣe, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìgbáralé ènìyàn ma ń nííṣe pẹ̀lú fífi ẹnìkan tàbí àwọn ènìyàn láti mú ǹkan tó ti bàjẹ́ bọ̀ sípò. Mo máa pe èyí ní níní ipá lórí àwọn ènìyàn.

Ọlọ́run nìkan ló ní agbára àti ipá láti bá àwọn àìní wa pàdé. Ibi tí wàhálà ti ma ń dé ni igba tí a bá takú sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn kí a tó lọ sá bá Ọlọ́run. Nínú Ìwé Mímọ́, a ríi kà bí Ọlọ́run ti lo ènìyàn láti mú ìlérí rẹ̀ ṣe nínú ayé àwọn tirẹ̀. Ṣùgbọ́n, kò sí ibi tí a kọ ọ́ sí wípé Ọlọ́run fojú-ire wo àwọn tó fi ènìyàn rọ́pò Rẹ̀. Kódà, ìdàkejì èyí ló wà ní àkọsílẹ̀; a ti ṣẹ̀dá òrìṣà ìmọ̀lára nìyẹn. Ìfẹ́sódì àwọn òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ ipele ìbọ̀rìṣà lọ́nà tirẹ̀.

Àlà tíńríń ló wà láàárín jíjẹ ìgbádùn ìbáṣepọ̀ ojúkoojú tàbí àǹfààní ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ lórí ayélujára àti ìsoríkọ́lẹ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ tó mú ìmọ̀lára dání tàbí ìfara-ẹni wé ẹlòmíràn. Àwọn ènìyàn àti ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú wọn jẹ́ ẹ̀bùn tí a ní ọrẹ-ọ̀fẹ́ láti jẹ̀gbádùn. Àmọ́ a ní láti ṣọ́ra kí a má gba ìmọ̀lára láàyè láti ní ipá tí yóò yọrí sí ìkárísọ, ìdáwà, ìlára, iyèméjì, tàbí ìbẹ̀rù lórí wa.

O ní láti rán ara rẹ létí wípé, nínú Kristi, o ní ìpèsè ohun gbogbo tí o nílò. O kò nílò láti gbójú lé ohun kan látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn kí o tó rí ara rẹ bí ènìyàn pípé.

Ǹkan tàbí ènìyàn wo lò ń gbójú lè fún iyì ọmọnìyàn rẹ?

A lérò wípé ètò yí fún ọ ní ìwúrí. Fún àlàyé síwájú síi nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí, fọwọ́ ba here.  

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

A U-Turn From Emotional Issues

Ti ayé rẹ̀ bá yàtọ̀ sí ètò Ọlọ́run, dandan ni kí o kọjú ìṣòro àti ìdààmú. Ti ẹ̀dùn ọkàn bá borí ẹ, tó bẹ̀rẹ̀ sì ni nípa lórí àlàáfíà rẹ, wàá ri pe o ti tì ra re sínú àhámọ́ tó ṣòro láti jade kuro. O nilo láti wá iwọntunwọnsi ki o si gbẹkẹle Ọlọ́run. Je ki Tony Evans salaye bó o ṣe lè lómìnira ọkàn.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Urban Alternative (Tony Evans) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tonyevans.org/