Ìyípadà Láti Ṣẹ́pá Àwọn Ìdààmú ỌkànÀpẹrẹ

A U-Turn From Emotional Issues

Ọjọ́ 1 nínú 3

Ti ayé rẹ̀ bá yàtọ̀ sí ètò Ọlọ́run, dandan ni kí ó kọjú ìṣòro àti ìdààmú. Ti ẹ̀dùn ọkàn bá borí ẹ, tó bẹ̀rẹ̀ sìn nípa lórí àlàáfíà rẹ, wàá rí pé ó ti tì ra re sínú àhámọ́ tó ṣòro láti jade kuro. Ó nílò láti wá iwọntunwọnsi ki ó si gbẹkẹle Ọlọ́run. Je ki Tony Evans salaye bó ṣe lè lómìnira ọkàn.

Àwon ẹ̀dùn jẹ́ sí ọkàn nǹkan ti imọ-ara jẹ́ sí ara. Wọn ṣe àfihàn èrò ọkàn nípa àwon ipò ìgbésí ayé. Àwon èèyàn tó ti ṣìna pẹ̀lú ẹ̀dùn wọn ń tiraka láti làájá, won lè sọ̀rètí nù, kọ si máa rò pé aláìníláárí àti àìlólùrànlọ́wọ́ ní won.

Níní ẹ̀dùn ọkàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kò túmọ̀ sí pé odi agbára ń bẹ láyé rẹ. O fihàn pé ìdẹkùn òdì tó tí borí ẹ ṣòro láti sálà, tó tí wà fa ìrẹ̀wẹ̀sì tí a kò kápá rẹ̀, ìsoríkọ́ àti ìbànújẹ́.

Dípò kó ṣe ohun tí ọpọlọpọ èèyàn ń ṣe (bibo odi agbára ọkàn mọ́lẹ̀ nipa lilo oògùn líle, síṣe fàájì, ìbálòpọ̀ ìṣekúṣe, tàbí owó ìlòkulò), ó ṣe pàtàkì láti ṣàwárí ìdí tó fi ń dojúkọ àwon ìṣòro yìí kó lè borí wọ́n. Lóòótọ́, kò sí lètò Ọlọ́run pé kó kojú ẹ̀dùn ọkàn rárá.

Dípò ìyẹn, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí ayé ni kíkún nínú Kristi fún ọ. Jésù sọ pé, “Èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.” (Jòhánù 10: 10b). Kò pè ọ láti gbé ní àìṣẹ́gun. Ó fẹ́ kó mọ̀ kí ó sì nígbàgbọ́ pé Òun ní Ẹni tó ń ṣàkóso ohun gbogbo, àti tó ń ṣe àbójútó ìgbésí-ayé rẹ. Tí ayé àìnípẹ̀kun t’Ọlọ́run ti ṣèlérí yìí ó bá tẹ̀ ọ lọ́wọ́, àkókò tí tó láti ṣàyípadà. Padà sọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kó sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣàfihàn ọ̀nà tó tí kùnà ní ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ̀ tó wá ṣokùnfà ìdààmú ọkàn. Ọlọ́run fẹ́ ran ẹ lọ́wọ́ láti rí èrò àlàáfíà ti Ó ní sí ọ, A sì mú iṣẹ́ ìyanu yọ nínú ìṣòro.

Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀dùn ọkàn wà ti o dà bíi pé ó lágbára lórí ìgbésí ayé rẹ? Ṣó ti ṣe tán láti fi wọn lè Ọlọrun lọ́wọ́?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

A U-Turn From Emotional Issues

Ti ayé rẹ̀ bá yàtọ̀ sí ètò Ọlọ́run, dandan ni kí o kọjú ìṣòro àti ìdààmú. Ti ẹ̀dùn ọkàn bá borí ẹ, tó bẹ̀rẹ̀ sì ni nípa lórí àlàáfíà rẹ, wàá ri pe o ti tì ra re sínú àhámọ́ tó ṣòro láti jade kuro. O nilo láti wá iwọntunwọnsi ki o si gbẹkẹle Ọlọ́run. Je ki Tony Evans salaye bó o ṣe lè lómìnira ọkàn.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Urban Alternative (Tony Evans) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tonyevans.org/