Ìyípadà Láti Ṣẹ́pá Àwọn Ìdààmú ỌkànÀpẹrẹ

A U-Turn From Emotional Issues

Ọjọ́ 2 nínú 3

Jẹ́kí n mú òtítọ́ kan nípa àwọn ìmọ̀lára wá sí ìrántí rẹ: wọn kò ní orí tí wọ́n ń rò. 

Wọn kì í ronú. Ní ṣe ni wọ́n kàn ma ń fèsì. Ìmọ̀lára ní láti ṣe àyálò èrò-ọkàn fún ìrunisókè. Fún ìdí èyí, ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó bá ń darí èrò-ọkàn rẹ, ni yóò darí ìhùwàsí rẹ. Àwọn ìmọ̀lára rẹ a máa ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ìdarí látinú ìhà tí o kọ sí àwọn ìpènijà ayéè rẹ. Nítorí náà, tí o bá fẹ́ kápá àwọn ìmọ̀lára rẹ àti láti borí àwọn ipá tí ìmọ̀lára ní lórí ayé rẹ, o ní láti kọ́kọ́ kápá ìrònú rẹ. 

Nígbà tí èrò-ọkàn rẹ bá wà ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ Ọlọ́run, o máa ní ìtúsílẹ̀.

Bejú wo inú dígí. Ẹni tí ò ń wò níbẹ̀ ti di kíkàn mọ́ àgbélébùú, a ti sìn ín, ó sì ti jíǹde pẹ̀lú Kristi. Lójú Ọlọ́run, nígbà tí Jésù kú ní ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, bẹ gẹ́gẹ́ ni ìwọ pẹ̀lú kú. Nígbà tí a sin ín, o dùbúlẹ̀ nínú ibojì pẹ̀lú Rẹ̀. Nígbà tó jíǹde, ìwọ pẹ̀lú jíǹde. Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé àìpẹ́ yìí ni o gba Jésù sínú ayé rẹ, Ọlọ́run mú ọ jẹ àǹfààní ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ sí Jésù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn èyí tó ti wá di ara ìrírí ìgbàgbọ́ rẹ.

Sátánì jẹ́ ọ̀gá nínú gbígbin àwọn èrò tí yóò mú ọ rò wípé ìwọ lo ni ara rẹ sí ọ lọ́kàn. Bóyá o máa ń gbọ́ ọ tí yóò sọ ọ̀rọ̀ bíi, “N kò lè borí fífojú kéré ara-ẹni àti páńpẹ́ fífi ara mi wé ẹlòmíràn. N kò lè bọ́ nínú ìgbèkùn ìmọ̀lára yìí. N kò lè dáwọ́ àwọn èrò ìbànújẹ́ yìí dúró.” Ó lè sọ àwọn ǹkan wọ̀nyí sí ọ, tàbí kó tilẹ̀ jẹ́ ìwọ lò ń sọ wọ́n sí ara rẹ, àmọ́ láti lè borí wọn, o ní láti dẹ́kun gbígba àwọn irọ́ wọ̀nyí gbọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lè jẹ́ òtítọ́ nígbà tí ìṣẹ̀dá rẹ àtijọ́ ṣì wà láyé, àmọ́ ẹni àtijọ́ọ nì ti kú lórí igi àgbélébùú pẹ̀lú Kristi. O ti di ẹ̀dá titun ní gbogbo ọ̀nà (Kọ́ríńtì Kejì 5:17).

Àwọn irọ́ wo nípa ara rẹ ni ò ń gbàgbọ́?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

A U-Turn From Emotional Issues

Ti ayé rẹ̀ bá yàtọ̀ sí ètò Ọlọ́run, dandan ni kí o kọjú ìṣòro àti ìdààmú. Ti ẹ̀dùn ọkàn bá borí ẹ, tó bẹ̀rẹ̀ sì ni nípa lórí àlàáfíà rẹ, wàá ri pe o ti tì ra re sínú àhámọ́ tó ṣòro láti jade kuro. O nilo láti wá iwọntunwọnsi ki o si gbẹkẹle Ọlọ́run. Je ki Tony Evans salaye bó o ṣe lè lómìnira ọkàn.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Urban Alternative (Tony Evans) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tonyevans.org/