Ọlọrun, Èmi Ńkọ́?Àpẹrẹ

God, What About Me?

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ṣe Àwọn Àdúrà Mi Ǹsisẹ́? 

Ǹjẹ́ a ti fún ọ ní ohun kàn tí èsì rẹ sì jẹ́, "ELÉYÌ kìí ṣé ohun tí mo gbà ààwẹ̀ lè lórí!" Ó ní ìsẹ́ra fún oúnjẹ́, ó gbàdúrà, ó sì ké pe Ẹlẹda, lẹhin gbogbo ìwọ̀nyí, àbájáde rẹ̀ wá jẹ ìdàkéjì ohun ti o ń gbàdúrà fún. Irú ìrírí bí eléyì lè mú wá béèrè bóyá kí a dá àdúrà dúró kí a sì gbé ọkàn lè ńkan míràn tàbí ẹ̀wẹ̀ kí a gba àdúrà" tí kò léwu" tí kò sì ní mú idagbasoke bá ìgbàgbọ́ wá.

Òtítọ́ ìbè ni pé, Ọlọ́run kò nílò wá láti dáàbò bo orúkọ rere Rẹ̀ nípa bí a ṣe ń béèrè ohun tí kò léwu tàbí rọrùn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Pẹ̀lú isaro yí, a fi òpin sí agbára Ọlọ́run láti ṣe ohun wọ́ọ̀ní tí kò séesé àti láti jẹ kí ògo àti agbára Rẹ̀ di mímọ ni ayé yí. Ọlọ̀run fi hàn mí pé nigbati mo bá gbàdúrà fún ohun tí mo nílò, bí ó ti wù kí ó tóbi tàbí kéré tó, mo gbé ìwọ̀n lè igbagbọ mi pé Ọlọ́run ti o lágbára láti fí tọkàntọkàn ṣe ohun gbogbo ni. Ọkàn mi pẹ̀lú ti gbaradì láti fi ọpẹ tí ó yẹ fún un. Ọlọ̀run tí kìlọ̀ fún mi pẹ̀lú ni kò pẹ̀ kò pẹ́, láti kiyesara fún ẹrú ijakulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń gbàdúrà. Ọlọ́run fi hàn mí pé eléyì lè ṣe ọ̀gangan ìdènà àdúrà mí. Ọlọ̀run yíò gbọ́ àdúrà, àti wípé bí kò tilẹ̀ dáhùn gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ní ìrètí sì, mo mọ́ pé Òun yíò gbá gbogbo ògo gẹgẹ bí ó ti sọ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

A kò ní ànfàní láti gba àwọn ẹ̀dùn ọkàn wá láyè láti síwájú wá nínú àdúrà. Àwọn ẹ̀dùn-ọkàn wá lè ṣe okùnfà kí á gbàdúrà tí yíò mú ìparun bá ẹnikẹ́ni tí ó wà "ní ìdí" irú ipò bẹ́ẹ̀ láìrò tẹ́lẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a bá ń wá ìmò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa ipò tí a wà, àwa yíò mọ bí ó bá jẹ́ láti ọwọ ọta ni tàbí ètò láti ọ̀dọ̀ Baba ti o tobi ti o si mọ ohun gbogbo.

Fún àpẹẹrẹ, Jésù Kristi nínú ọgbà Getisimani: bí Ò ṣé ń gbàdúrà, kò gbàdúrà tí ó lòdì sí àwọn Farisí, tàbí Júdásì tí wọ́n dà bí pé wọn dúró bi elénìní "lẹ́hìn" Rẹ̀. Àdúrà Rẹ̀ dúró lórí ìfẹ́ Ọlọ́run, pàápàá nínú ìrora Rẹ̀. 

Nítorí náà ìbéèrè yẹn láti jẹ́, ÌFẸ́ tani àwọn àdúrà rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún?

IDAGBASOKE   Bọtini: ọjọ_4 ọjọ́_4
Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

God, What About Me?

Nígbà tá a bá rò pé a ti jìnnà síbi tá a yẹ ká máa gbé, tí ohùn ìfiwéra sì túbọ̀ ń dún bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a kì í sábà rí i pé Ọlọ́run wà láàárín wa. Àwọn àkókò yìí gan-an ni ìgbàgbọ́ wa máa ń lágbára jù lọ. Ka àdúrà yìí kó o sì rí ìṣírí gbà bó o ṣe ń dúró de Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ David & Ella fún mímú kí ètò yìí ṣeé ṣe. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: http://davidnella.com

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ