Ọlọrun, Èmi Ńkọ́?Àpẹrẹ

God, What About Me?

Ọjọ́ 3 nínú 5

h3>Àkókò Ìfojúsọ́nà Mi

Ní àkókò tí ó ń fojú sọ́nà yí, rántí wípé gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run tí ó gá jùlọ̀, gbogbo àkókò ló jẹ́ àkókò rẹ̀. Èrò tí ó já sí wípé àkókò tí ń kán bá lọ bí a ṣe fẹ nìkan ni àkókò wá kò dára tó o sì tún ní ewu pẹ̀lú.

Nígbàtí Dáfídì ń tọ́jú agbo àgùntàn, àsìkò yìí jẹ "àkókò" rẹ̀ àti ìgbà tí a tí Jósẹ́fù mọ́ inú túbú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀, àsìkò yìí náà jẹ "àkókò" rẹ̀ pẹ̀lú.

Ní àkókò ìfojúsọ́nà wá yí, ohun tí a fí ojú rí yíò jẹ́ ìpèníjà ìgbàgbọ́ wá nínú Ọlọ́run nítorí pé ìgbà gbogbo kọ́ ni ohun tí a fí ojú rí lè jẹ́ ẹ̀rí ohun tí a gbà gbọ́ láti ṣe fún wa. Ní ìgbà wọnnì rántí wípé a ń gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ kìí ṣe nipa rírí. A gbé ìpinnu wá kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, kìí ṣé nípa ìdíwọ̀n àwọn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́wọ́ lọ́wọ́? Bí a ṣe ń fojú sọ́nà a ńkọ̀ bí a sé ń tẹrí ìfẹ́ wá ba - àwọn àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun tí yíò sẹlẹ - àti pàápàá jù lọ ibi tí Ọlọ́run fẹ̀ mú wá dé. Ní ìkáwọ́ Rẹ̀ ní ààbò tó dájú wá fún wa, nítorí pé Òun nìkan ní ó ní agbára láti wá loni, ní ọ̀la àti ọdún tí ó ńbọ̀ pẹ̀lú.

Ìfojúsọ́nà ńṣé àfihàn kíni àti tani a ní láti jọ́sìn fún. Ó tún ńsé àfihàn ìbẹ̀rù tí ó fí ìdí múlẹ̀ gidi àti pàápàá àwọn àníyàn ìgbàgbọ́ tí ó fí ara sin. Nígbàtí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ńfojúsọ́nà láti dé ilẹ̀ ìlérí, wọn lépa ìtẹ́lọ́rùn tí yíò wá lẹ́sẹ̀ kẹ́sẹ̀ nítorí pé ohun tí ó jọ wọn lójú nìyẹn. Nwọn fẹ́ padà sí oko ẹrú dípò kí wọn fí ojú sọ́nà àti kí wọn ní ìfaradà ìrìn-àjò wọn nítorí wípé ọlọ́run miran ni wọn ń sìn ní ọkàn wọn. 

Ìfojúsọ́nà kò já ṣòfò. Ìlérí Ọlọ̀run kò ní sé aláìsẹ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì -Ó ńgbaradì fún wọn ní. Nígbàtí ó bá rí pé ìwọ kò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àyè tí ó wà, kini ohun náà tí ìwọ yíò ṣé? Ìdáhùn sí ìbéèrè yí ṣé àfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńkan nípa ọkàn rẹ̀.  

Lákókò ìfojúsọ́nà wá, Ọlọ́run ń múra fún wá nítorí ohun tí a lè bá pàdé ni ọjọ iwájú. Ojoojúmọ́ ni Ọlọ́run ń bá wa ṣọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí a bá dojú kọ ọjọ iwájú tí a kò náà ní Ẹni tí ó jẹ atọ́nà wá nígbà náà a kò ní gbọ́ ohùn Rẹ̀. Nítorí náà àsìkò yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n a ó sì di ẹni tí a pín lẹ̀mí àti ẹni tí kò rójútú ara rẹ̀ bí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ wá nítorí pé a kò gbà ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí a sọ pé Ó rán wa nísẹ́. 

Ìdàgbàsókè   Botini: ọjọ_3 Ọjọ́_3
Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

God, What About Me?

Nígbà tá a bá rò pé a ti jìnnà síbi tá a yẹ ká máa gbé, tí ohùn ìfiwéra sì túbọ̀ ń dún bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a kì í sábà rí i pé Ọlọ́run wà láàárín wa. Àwọn àkókò yìí gan-an ni ìgbàgbọ́ wa máa ń lágbára jù lọ. Ka àdúrà yìí kó o sì rí ìṣírí gbà bó o ṣe ń dúró de Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ David & Ella fún mímú kí ètò yìí ṣeé ṣe. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: http://davidnella.com

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ