Ìrètí Ìyè: Ìfojúsọ́nà fún ÀjíǹdeÀpẹrẹ

Living Hope: A Countdown to Easter

Ọjọ́ 3 nínú 3

“Tèlé Mi.”

Peteru jókòó ní ìbìnújẹ́ àti òkùnkùn, ó n gbé àwọn ọjọ́ ayé rẹ̀ nínú ìdákẹ Ọlọ́run. Ó ti sẹ́ Jésù ní gbangba ṣáájú kí wọ́n tó fa Jésù lọ láti kàn-án mọ́ àgbélèbú. Fún àwọn ọjọ́ díẹ̀ sí àkókò yìí, Peteru ní láti s'àṣàrò ìbìnújẹ́ àti ẹ̀bi rẹ láì sí ìrètí kankan pé ìrora náà yóò dá. 

Ṣùgbọ́n ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, ibojì Jésù wà ní òfo, a sì tún yí òkúta náà kúrò. Bí Peteru ṣe n sáré ní ìbẹ̀rù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn míràn - ní ìgbìyànjú láti ṣe ìlànà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ náà - l'òjijì ni Jésù farahan Peteru ní kíkún láàyè

Dípò kí ó jẹ́ kí Peteru gbé pẹ̀lú ìtìjú àwọn àṣìṣe rẹ̀ tí ó kọjá, Jésù fà á sẹ́yìn, ó sì béèrè ìbéèrè kan tí yóò ru Peteru sókè sínú ètò Ọlọ́run fún ayé rẹ̀: 

“Ṣé o n'ìfẹ́ẹ̀ mi?”

Pẹ̀lú ìbéèrè yìí, Jésù pe Peteru láti tún jẹ́ ẹ̀ri sí ìbáṣepọ̀ tí ó ti sẹ́. Agbára Jésù lórí ikú àti òkùnkùn túmọ̀ sí pé àwọn àṣìṣe Peteru tí ó kọjá kò ní láti jọba lé è lórí mọ́. Ó ṣì lè gba ìpè orí àyè rẹ̀ kí ó sì di adarí tí Jésù mọ̀ nígbà gbogbo pé ó lè jẹ́. 

Bíi Peteru, o ní ànfàní láti sọ “bẹ́ẹ̀ni” sí níní ìfẹ Jésù àti sí ìfẹ́ Rẹ̀ sí ọ. Láì bìkítà bí ayé rẹ ṣe rí, tàbí bí o ṣẹ rò pé o jìnnà sí Jésù sí, kò sí nkankan tí ó lè yà ọ́ kúrò nínú ìfẹ́ Rẹ̀. Àwọn àṣìṣe rẹ tí ó kọjá tàbí àwọn ìṣòro lọ́wọ́lọ́wọ́ kò lè pinnu ìdí rẹ̀ nígbà tí igbesi ayé rẹ fìdí múlẹ̀ nínú Kristi nìkan. 

Àjínde fi dá wa l'ójú pé kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àṣìṣe tí ó le fún Ọlọ́run láti rà padà. Kò sí ìbẹ̀rù tí Jésù kó lè ṣẹ́gun àti ayé tí kò lè mú l'ára dá. Kò sí òkùnkùn tí ó lè dúró lòdì sí agbára Ọlọ́run tí ó jínde tí ó ṣẹ́gun ikú nítorí ti wa. Kò sí ohun tí Ọlọ́run wa kò lè ṣe. 

Gb'àdúrà: Jésù, o ṣeun nítorí O ṣẹ́gun ikú fún mi. Mo dúpẹ́ wípé kò sí ohùnkan tí ó lè yà mí kúrò nínú ìfẹ́ Rẹ̀, àti pé kò sí àṣìṣe tí ó lè mú mi yẹ̀ nínú àwọn ètò Rẹ. L'óni, ràn mi létí eni tí O pè mí láti jẹ́. Àti pé nígbà tí mo bá bẹ̀rẹ̀ síí ní rílára pé n kò yẹ, ràn mí l'ọ́wọ́ láti rántí láti ronú lórí àjínde Rẹ̀, kí inú mi dùn pé Ìwọ nìkan ni ìgbàlà mi. Mo nífẹ̀ẹ́ Rẹ, mo sì yàn lónìí láti tẹ̀lé Ọ.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Living Hope: A Countdown to Easter

Nígbà tí òkùnkùn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀, irú ìhà wo ló yẹ láti kọ? Ri araà rẹ sínú ìtàn ọdún àjíǹde ní ọjọ́ mẹ́ta tó ń bọ̀, pàápàá ní àwọn àkókò tí ó bá ńṣe ọ́ bíi wípé a ti kọ̀ ẹ́ sílẹ̀, tàbí wípé a kò kà ọ́ yẹ.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ