Ìrètí Ìyè: Ìfojúsọ́nà fún ÀjíǹdeÀpẹrẹ

Living Hope: A Countdown to Easter

Ọjọ́ 2 nínú 3

“Mọ́kàn le.” 

Bíbélì kò tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò ikú àti àjíǹde Jésù. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ wípé àkókò ayẹyẹ ọdún Ìrékọjá ni ìṣẹ̀lẹ̀ yí wáyé: ọdún ọlọ́ṣẹ̀ kan ní ìrántí ìgbà tí Ọlọ́run tú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú. 

Lákòókò ayẹyẹ yìí, àwọn Júù ma ń pín oúnjẹ pẹ̀lú ìrúbọ àgùntàn tí kò l'ábàwọ́n ní tẹ́mpìlì, lẹ́yìn èyí tí wọn yóò wá sinmi lọ́jọ́ Olúwa. Ọjọ́ kan ṣáájú Ìsinmi yìí ni a tẹ òkú Jésù sínú ibojì. 

Fojú inú wo bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò ti rí lára àwọn ọmọ lẹ́yìn Jésù lákòókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kiise wípé wọ́n pa ọ̀rẹ́ wọn tímọ́ tímọ́ láìṣẹ̀ nìkan, àmọ́ àyè kò sí fún wọn láti ṣọ̀fọ̀ Rẹ̀ títí ọjọ́ ìsinmi fi parí. 

Ohun tí kò yé àwọn ọmọ lẹ́yìn nígbà náà ni wípé ìrírí wọn ń bọ̀ wá d'ìtàn tó máa gbayé kan–èyí tí í ṣe ètò fún ìràpadà gbogbo ènìyàn. Ọlọ́run ń wòye bí àjíǹde náà tí ń súnmọ́, bí àwọn ọmọ lẹ́yìn kò tilẹ̀ ríi. 

Ìsinmi a máa rán wa létí wípé Ọlọ́run ló ba lórí ohun gbogbo. Ìsinmi a sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi ǹkan pàtàkì ṣe àfojúsùn: ìyẹn Ẹni tó ṣèlérí láti bá gbogbo àìní wa pàdé. Nígbà tí a kòbá kù gìrì lákòókò ìpèníjà, èyí jámọ́ ṣíṣe ìjọsìn sí Ọlọ́run. 

Ohunkóhun tí ìbá máa ṣẹlẹ̀ láyìíká rẹ lónìí, gbìyànjú láti sinmi lé Ọlọ́run–pàápàá nígbà tí àwọn tó yí ọ ká bá dìbò fún àníyàn. Kò sí ohun kan tó ṣòro íṣe fún Un.

Gbàdúrà: Jésù, ràn wá lọ́wọ́ lónìí, láti sinmi lé ọ. Mo mọ̀ wípé O kápá gbogbo ìpèníjà tó yí mi ká. Ìwọ nìkan ni ìrètí mi nítorí Ìwọ ni ìgbàlà mi. Mo gbàgbọ́ wípé gbogbo ẹ̀dùn ọkàn mi lo ti fi ìdáhùn sí, bí mo tilẹ̀ ń dúró fún èsì. Torí náà lónìí, mo yàn láti tẹjú mọ́ Ọ. Ní orúkọ Jésù, Àmín.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Living Hope: A Countdown to Easter

Nígbà tí òkùnkùn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀, irú ìhà wo ló yẹ láti kọ? Ri araà rẹ sínú ìtàn ọdún àjíǹde ní ọjọ́ mẹ́ta tó ń bọ̀, pàápàá ní àwọn àkókò tí ó bá ńṣe ọ́ bíi wípé a ti kọ̀ ẹ́ sílẹ̀, tàbí wípé a kò kà ọ́ yẹ.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ