Ìrètí Ìyè: Ìfojúsọ́nà fún ÀjíǹdeÀpẹrẹ
“Èíṣe tí O fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
Fojú inú wo Jésù bó ti kọ́ sórí igi àgbélébùú. Ọ̀nà kan tó fi ń ráyè mí ni láti fi ìṣó ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ti ara Rẹ̀ sókè.
Bí ọjọ́ náà ti ń súré lọ s'ópin, Ó gbìyànjú láti fa ara rẹ̀ sókè lẹ́ẹ̀kan si láti pariwo wípé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èíṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
Tí a ò bá ní tan arawa jẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ gbogbo wa ló ti ní ìdojúkọ tí yóò mú wa bèrè wípé: “Ibo lojúù Rẹ wà Where are You in this? me?”
Ìhà wo lóye kí a kọ nígbà tí a bá ri wípé àwa nìkan ló dá wà, ní àníyàn, tàbí jẹ́ ìkọ̀sílẹ̀?
A máa ṣe àkíyèsí wípé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lórí igi àgbélébùú ni a fà yọ látinú Orin Dáfídì 22—àsọtẹ́lẹ̀ ìkọminú tí Ọba Dáfídì kọ. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ona, orin yìí dá lóríi Jésù, ṣùgbọ́n ó tún wá pèsè ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí a lè máa tẹ̀lé nígbà tí a bá kojú ìkọ̀sílẹ̀:
1. Má ṣe fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún Ọlọ́run.
Ìbáṣepọ̀ a máa jẹyọ látinú ìṣòóótọ́. Fún ìdí èyí tí ó bá ńṣe ọ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, sọ fún Un bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Bèrè àwọn ìbéèrè rẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí o sì ṣètò ọkàn rẹ fún èsì látọ̀dọ̀ Rẹ̀.
2. Fi ògo fún Ọlọ́run ní gbogbo ọ̀nà.
Ìmọ̀lára wa kòní kí Ọlọ́run pàdánù ẹ̀tọ́ Rẹ̀ láti gba ìjọsìn wa. Kódà, lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa ń yanjú àwọn ìdojúkọ níbi ìjọsìn. Nígbà tí a bá fi ìwàláàyè Ọlọ́run ṣe àfojúsùn, ìrísí wa ma yípadà–bí ipò tí a wà kò tilẹ̀ yípadà.
3. Rán Ọlọ́run létí nípa àwọn ìlérí Rẹ̀.
Jálẹ̀ Orin Dáfídì 22, ni Dáfídì ti ń sọ f'Ọ́lọ́run wípé, “Mo mọ ẹni tí ìwọ íṣe. Níwọ̀n ìgbà ìwà Rẹ kò yípadà, gbà mí bí O ti gba àwọn ènìyàn ìgbàanì.” Mímú àwọn ìlérí Ọlọ́run wá sí ìrántí kiise nípa ìgbàgbọ́ nìkan, àmọ́ ó tún ń mú wa rántí ìwà ìṣòóótọ́ Ọlọ́run.
Parí parí ẹ̀, ìṣòóótọ́ Ọlọ́run ní ìfarahàn gẹ́gẹ́bí ènìyàn nígbà tí a kan Jésù mọ́ àgbélébùú. Jésù mọ̀ọ́ mọ̀ọ́ dá jẹ̀yà orí igi àgbélébùú kí a ba lè ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run títí láéláé. Jésù ló jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Orin Dáfídì 22. Àti wípé, níwọ̀n ìgbà tó ti farada ìyapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, a kò nílò láti kojú irú ìpèníjà yí.
Wá àkókò láti ṣe àṣàrò nípa ìfarajìn tí Jésù ṣe fún ẹ.
Gbàdúrà: Jésù, o ṣé tí o gbà mí là lọ́wọ́ ìyapa ayérayé. Nítorí ìwọ ti kojú ìyapa kúrò lọ́dọ̀ Baba Rẹ ni a kò ṣe nílò láti ní irú ìrírí yìí. Lónìí, ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àṣàrò lórí bí ìfarajìn Rẹ ti nípọn tó, àti láti fi ògo tó yẹ ọ́ fún ọ. Ohunkóhun tí ń báà ma là kọjá, ojojúmọ́ ni ọpẹ́ yóò máa t'ọ̀dọ̀ mi wá. Fún ìdí èyí, mo pinu láti yìn Ọ́ lónìí àti títí ayérayé. Ní orúkọ Jésù, Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nígbà tí òkùnkùn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀, irú ìhà wo ló yẹ láti kọ? Ri araà rẹ sínú ìtàn ọdún àjíǹde ní ọjọ́ mẹ́ta tó ń bọ̀, pàápàá ní àwọn àkókò tí ó bá ńṣe ọ́ bíi wípé a ti kọ̀ ẹ́ sílẹ̀, tàbí wípé a kò kà ọ́ yẹ.
More