Gbígbọ́ lati Ọ̀run: Títẹ́ Etí S'ílẹ̀ Sí Olúwa Nínú Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́Àpẹrẹ

Òtítọ́ Láti Inú Ẹ̀mí
Lẹ́yìn tí mo ti di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo j'áwọ́ nínú lílọ sí ilé-ìjọsìn. Mo fẹ́ jẹ́ ẹni tí ó gb'áfẹ́, ilé-ìjọsìn kò sí gbọ́ afẹ́ tó fún mi. Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé e, mo ní ọ̀pọ̀ ìṣòro, mo sì ń hùwà ọ̀tẹ̀. Mo rántí ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo sì rántí bí Ọlọ́run ṣe ṣí òtítọ́ payá fún mi. Ọlọ́run lo òtítọ́ Rẹ̀ láti pe mi kúrò ninú òkùnkùn mi.
Ẹ̀mí Mímọ́ ń sọ, Ó sì ń fí òtítọ́ hàn fún onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́. Ní ìgbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba tí mo ti di ọlọ̀tẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ hàn mí. Mo wá rí i pé ọ̀nà òkùnkùn àti ikú ni mo ti rìn. Mo níílò ìmọ́lẹ̀ àti ìyè Ọlọ́run. Ó gba pé kí wọ́n dá mi dúró ní ilé-ìwé kí Ọlọ́run tó fi ara Rẹ̀ hàn mí. Ní àárín ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n dá mi dúró ní ilé-ìwé, Ẹ̀mí Mímọ́ bá mi s'ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó hàn kedere, Ó sì pè mí pé kí n yí padà kúrò nínú ìwàkiwà mi.
Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́, a kò dá nìkan wà. Ẹ̀mí Mímọ́ ń darí ìgbésẹ̀ wa, Ó sì ń bá wa s'ọ̀rọ̀. A níílò òtítọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́, Ẹ̀mí Mímọ́ sì ń fi í fún wa. Ṣùhbọ́n ní ìgbà mìíràn, a kì í fi etí sílẹ̀, a kì í sì í gbọ́. A gbà pé Ọlọ́run kì í s'ọ̀rọ̀. Ṣúgbọ́n, ṣé òótọ́ ni? Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé a kò ì tíì kọ́ bí a ṣe ń fi etí sílẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé mímọ́ di ààyè.
Kò ṣeé ṣe fún aláìṣòdodo kan láti tẹ́'wọ́ gba òtítọ́ láìjẹ́ pé í Mímọ́ ṣí ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ payá. Kò tún ṣeé ṣe láti gbé ìgbésí ayé òdodo láìjẹ́ pé Ẹ̀mí Òtítọ́ fi ohun tí ó jẹ́ òdodo hàn wá.
Olúkúlùkù ọmọlẹ́yìn Krístì ni a fún ní Ẹ̀mí Mímọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti la ojú wa sí ètò Rẹ̀. Njẹ́ a le lo àkókò díẹ̀ láti gbàdúrà pé kí Ẹ̀mí Òtítọ́ la ojú àwọn tí òkùnkùn ti fọ́ lójú? Baba Ọ̀run, O ṣeun fun È̩mí tí Ó ń sọ tí Ó sí ń ṣe àfihàn òtítọ́. Mo gbàdúrà pé Ìwọ yóò s'ọ̀rọ̀ kí o sì fi òtítọ́ Rẹ hàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ń rìn nínú òkùnkùn, Àmín!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Olúwa wà láàyè, Ó sì ń ṣiṣẹ́ ní óde òní, Ó ń bá olúkúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àmọ́ ní ìgbà míràn, Ó máa ń ṣòro láti rí I àti láti gbọ́ Ọ. Nípa yíyànnàná ìtàn ìrìn àjò ọkùnrin kan láti ní òye ohùn Ọlọ́run ní ìgbèríko Nairobi, ìwọ yíó mọ bí ó ti rí láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé E.
More