Gbígbọ́ lati Ọ̀run: Títẹ́ Etí S'ílẹ̀ Sí Olúwa Nínú Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́Àpẹrẹ

Hearing From Heaven: Listening for the Lord in Daily Life

Ọjọ́ 2 nínú 5

“Máa wí, Olúwa Nítorí tí Ìránṣẹ́ Rẹ ń Gbọ́.”

Ọlọ́run a máa bá àwọn ènìyàn Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ ní kedere ní gbogbo ìgbà. Nípasẹ̀ àwọn àlùfáà àti wòlíì, Ó ń fi òtítọ́ tí ń fúnni ní ìyè hàn fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ Rẹ̀ tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé E. Ó sì tún fẹ́ràn láti máa bá àwọn ènìyàn Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀! Ṣùgbọ́n bí a kò bá lè rí, tí a kò sì lè gbọ́,ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi yíó di èyí tí ó ní akúdé.

Ǹjẹ́ o lè fi ojú inú wo òye ìyàn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́kọjá, kí ó tún lé ní ọdún, láìsí gbígbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Irú ipò báyìí dà bí i ipò àìnírètí. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan - an nìyîí nínú Sámúẹ́lì Kìnní. Ní ìgbà tí àwọn ènìyàn Olúwa ń fẹ́ láti gbọ́ ohùn Rẹ̀, Ó yàn láti fi ara Rẹ̀ hàn fún ọ̀dọ́kùnrin kan.

Ọ̀dọ́mọdékùnrin Sámúẹ́lị̀ kò ì tíì mọ ohùn Ọlọ́run. Nítorí náà ní ìgbà tí ó gbọ́ ìpè náà, Sámúẹ́lì dáhùn ní ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó mọ: ó sáré lọ sí ọ̀dọ̀ olùkọ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ ènìyàn! Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọgbọ́n Eli, Sámúẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ẹni tí ó ni ohún àti bí ohùn Rẹ̀ ṣe rí.

A lè mọ ohùn Ọlọ́run. A kàn ní láti mọ ohun tí ó yẹ kí á máa fi etí sí!

Mo ka ìtàn yìí ní ìgbà tí mo wà ní ọmọdé ní ibi ètò Compassion International tí mo lọ, èyí sì fún mi ní ìṣírí gan - an. Bí mo ṣe ń gbé nínú ipò òṣì paraku, gbogbo ìgbà ni mo máa ń fẹ́ kí Ọlọ́run fi ara rẹ̀ hàn mí ní ọ̀nà ńlá àti alágbára yìí. Àmọ́ kíni màá ṣe bí Ó bá fi ara Rẹ̀ hàn fún mi lóòótọ́? Kíni yíó béèrè lọ́wọ́ mi?

Kọ́ láti fi etí sí Ohùn Òtítọ́ dípò iyèméjì, ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àìnírètí. Kọ́ etí rẹ láti gbọ́ ìhìnrere Rẹ̀! Ọlọ́run fi Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fún wa nínú ìwé--ka òtítọ́ Rẹ̀, tí a ṣe fún ọ, nínú Bíbélì. Wá olùkọ́ tí ó mọ ohùn Olúwa kí o sì kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn. Da ara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn onígbàgbọ́ tí ó mọ Olúwa tí wọ́n sì ní ìfẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì lè gbé ọ ró nínú wíwá ohùn Olúwa.

Élì kọ́ Sámúẹ́lì bí ó ṣe yẹ kí ó dáhùn sí ohùn Olúwa: “Máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.” Ìdáhùn rẹ mà dára o. Ó yẹ kí àwa náà dáhún bákan náà ní ìgbàkígbà tí a bá gbọ́ tí Ó ń s'ọ̀rọ̀.

Olúwa fẹ́ fi ara Rẹ̀ hàn fún àwọn ènìyàn Rẹ̀. Ó fẹ́ tọ́ wa s'ọ́nà kí Ó sì darí wa. Ǹjẹ́ o mọ ohùn Ọlọ́run? Ǹjẹ́ o ń wá ìtọ́sọ́nà nípa àwọn ìgbésẹ̀ tí ó kàn ní ìgbésí ayé rẹ, iṣẹ́ ajé re, ẹ̀kọ́ re, ìdílé rẹ tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ? Bí ó bá jẹ́ pé àdúrà rẹ nìyìí, gbàdúrà pèlu mí, “Máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Hearing From Heaven: Listening for the Lord in Daily Life

Olúwa wà láàyè, Ó sì ń ṣiṣẹ́ ní óde òní, Ó ń bá olúkúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àmọ́ ní ìgbà míràn, Ó máa ń ṣòro láti rí I àti láti gbọ́ Ọ. Nípa yíyànnàná ìtàn ìrìn àjò ọkùnrin kan láti ní òye ohùn Ọlọ́run ní ìgbèríko Nairobi, ìwọ yíó mọ bí ó ti rí láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé E.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Compassion International fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.compassion.com/youversion