Já Ara Rẹ Gbà Kúrò Lọ́wọ́ Owú Ètò Kíkà Ọlọ́jọ́-Mẹ́fà Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ

Break Free From Envy a Six-Day Reading Plan by Anna Light

Ọjọ́ 3 nínú 6

Ọjọ́ 3—Owú láti inú Ọkàn

Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ti bá ọ̀rẹ́ tàbí ojúlùmọ̀ kan sọ̀rọ̀ rí dé bíi pé ẹ m'ẹ́nu ba àmúyẹ ẹnìkan, oríire rẹ̀, tàbí àṣeyọrí irú ẹni bẹ́ẹ̀? Irú èsì tó sábáà máa ń tẹ̀lée ni èyí tí yíò bu irú ẹni tí ẹ m'ẹ́nu bà bẹ́ẹ̀ kù.

"Ǹjẹ́ o gbọ́ pé ________ kọ ìwé?"

"Hẹnẹn, ṣèbí fúnraarẹ̀ ló ṣe àtẹ̀jáde rẹ."

“Ìjọ wọn ńgbèrú síi gidigidi."

“Báwo ni kò ṣe níí ríi bẹ́ẹ̀, ṣebí ìjọ aláfẹ lásán ni.

"Ó mà ti ṣò, tó gbá'ra mú gidi"

“Kò burú, ṣèbí iṣẹ́-abẹ ló fi yọ ọ̀rá ara kúrò.”

Irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí ba'ni l'ọ́kàn jẹ́, ṣùgbón èmi ni màá kọ́kọ́ j'ẹ́wọ́ pé mo ti sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí, ó sì dámilójú gbangba pé mo ti ní wọn l'érò rí pẹ̀lú.

Fífi ojú réénà ènìyàn báyìí lè fún wa ní ìwúrí fún ìgbà díẹ bí a ṣe ńgbìyànjú láti má jẹ kí ẹlòmíràn dára jù wá lọ, àmọ́ ohun tí èyí fihàn gbangba ni pé ọkàn wa kò l'ókun tó àti wípé a ò kun ojú òṣùwọ̀n tó l'ójú ara wa.

Francis Bacon sọ nípa òwú pé, “Àwa tí a kò t'ẹ̀wọ̀n tó nínú ohun àmúyẹ ti ẹlòmíràn ní máa ńgbà láti tẹ́ńbẹ́lú àṣeyọrí wọn.” A máa bá ẹnìkejì jẹ́, nínú ọ̀rọ̀wa, ọkàn wa, èrò wa àti ìṣe wa. Kò sí ọkankan nínú àwọn ohun wọnyí tí ó lè mú wa gbé ìgbé ayé àlàáfíà lẹ́kùnrẹ̀rẹ́ èyí tí o wà fún wa.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wa ló ní àbùdá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ńṣe ìtọ́kasí ògo Ọlọ́run. Àmọ́ l'ọ́pọ̀ ìgbà aráyé (tàbí àwùjọ, ojúlùmọ̀, alábàákẹgbẹpọ̀) kìí rí tàbí mọ rírì àbùdá ògo àrà-ọ̀tọ̀ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí a bá ńjowú, à ńdín ògo kù ni. À ńtako ẹ̀bùn ẹlòmíràn kó má bàá bo t'iwa mọ́lẹ̀.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé ẹlòmíràn kò lè ṣàì má ní jù wá lọ, wọn yíó ní àṣeyọrí ju wá lọ, tàbí kí wọn ní àmúyẹ jù wá lọ ní àwọn agbọn kan. Bẹ́ẹ̀ l'ayè rí. Kò sí ẹni tó ní gbogbo ǹkan tán, bí a baà níí purọ́, ìtẹ́lọ́rùn kò sí ní ayé wa yìí. Àmọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ló ní ohun àmúyẹ, ohun tó ni'wọ̀n, ohun tí ẹlòmíràn le jowú sí nínú wa tí àwa gan an kò ní'ran rẹ̀.

Ilépa náà kìíṣe fún wa láti jẹ́ "amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́”. Abala yìí láti inú ìwé àròsọAtlas Shrugged ṣe àlàyé rẹ̀ dáadáa. “Ṣé o mọ àmì ìdánimọ̀ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́? Òhun ni kí a máa ṣáátá àṣeyọrí ẹlòmíràn. Àwọn oníkanra aláìníkanṣe ti won ń lé fùrù kọkọ kí iṣẹ ẹlòmíràn máa baà dáa ju tiwọn lọ. Wọn a máa fẹ̀ hòò láti kọ̀rọ̀ kóńdú tí wọn wà pẹ̀lú èrò pé o ní ìdùnnú sí kìí ìmúyányán tìrẹ mú kí wọn wà lókùnkùn.”

Nígbàtí mo ka àyọkà yìí o mú mi l'ọ́kàn gidi nítorípé òtòṣì "amúgbálẹ́gbẹ̀" ní mo jẹ́ nígbà kan rí. Mo ní ìgbàgbọ pé àwọn ẹlòmíràn máa ń mọ̀ọ́mọ̀ f'ojú pa'mí rẹ́ látàríi pé wọn dára jù mí lọ-pé wọ́n kàn ń ṣe tiwọn. Mò ń jowú àwọn àṣeyọrí kan sùgbọ́n mi ò ní ìpòǹgbẹ láti dá ǹkan ṣe fúnraà mi. Mò ń jowú àwọn ẹ̀bùn àti àmúyẹ kan ṣùgbọ́n mi ò ní ojú-inú láti rí àwọn àsàyàn ẹbùn àti àmúyẹ tí mo ní. Àyọkà náà tẹ̀ síwájú pé, "Iran tí wọn ní {ìyẹn àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́} fún dídi ẹni ńlá ní ayé tí gbogbo ènìyàn yóò di àrùn fún wọn. Wọn kò mọ̀ pé irú ìran báyìí ní ìfìdímúlẹ àìgbéwọ̀n tó.”

Ṣé lóòótọ́ ni a fẹ́ irú ayé tí gbogbo ènìyàn yóò wà l'ábẹ́ ẹsẹ̀ wa? Báwo ni irú ayé báyìí yóò ti mẹ́hẹ tó? Ìdàgbàsókè ẹlòmíràn yẹ kí ó ru Ìdàgbàsókè tiwa sókè. Ṣùgbọ́n èyí kò lè ṣẹlẹ̀ tí a kò bá lè kọ́ láti mọ rírì, ṣe ìdíyelé àti ṣe àjọyọ̀ ìgbéga tí a rí nínú àti kí a mọ̀ pé àwọn ẹ̀bùn, àmúyẹ àti àbùdá tí Ọlọ́run fi fún wọn kìí ṣe láti mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kí á re'lẹ̀.

A lè nífẹ̀ sí ǹkankan nínú ẹlòmíràn, ṣùgbón tí a kò bá ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó nínú ẹni tí a jẹ́ dé bii pé kí a gb'oríyìn fún àti kí a fí ìfẹ́ tí a ní yìí hàn s'íta, a máa kẹ̀ nínú wa tó bẹ́ẹ̀ tí yóò di májèlé ti yóò jẹ wá run láti inú wá.

Ìdibàjẹ́ tí eléyìí yóò ṣe nínú ọkàn wa yóò ṣá ẹ̀mí wa l'ọ́gbẹ́. Ó yẹ kí a ṣe iṣẹ́ àṣekára láti hú àwọn èrò yìí jáde, kí a pa wọ́n tegbòtegbò, kí a sì wo bi wọn yóó ṣe sọ agbára nù lórí wa.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Break Free From Envy a Six-Day Reading Plan by Anna Light

Ní àkókò yí, ǹkan tó dára nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní wọ́n fihàn fún wa láti rí, àti wípé àfiwé tí a bá ṣe pẹ̀lú ayé tiwa a máa mú owú jẹyọ. O kò fẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa jọba nínú ayé rẹ, àmọ́ kí ló máa ṣe sí àwọn ìjàmbá tó lè wá nípasẹ̀ owú látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn sí ọ? Nínú ètò kíkà yí, o máa rí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà borí owú, pa ọkàn rẹ mọ́, pẹ̀lú òmìnira.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Anna Light (LiveLaughLight) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ lọ sí: http://www.livelaughlight.com