Já Ara Rẹ Gbà Kúrò Lọ́wọ́ Owú Ètò Kíkà Ọlọ́jọ́-Mẹ́fà Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ

Break Free From Envy a Six-Day Reading Plan by Anna Light

Ọjọ́ 6 nínú 6

Day 6— Kò Tọ̀nà 

Bóyá ìdínà tó tóbi jù lọ́nà láti wá òmìnira wa ni èrò pé ọjọ́ ọ̀la kò sí ní ìkáwọ́ wa. Ó wù wá kí á rò pé gbogbo nnkan wà ní ìkáwọ́ wa, ayé pàápàá jẹ́ kí á rò pé a lè ṣe é, ṣùgbọ́n ní òtítọ́, àwọn nnkan kan wà tí a kò lágbára lórí pé wọ́n ṣẹlẹ̀ tàbí kí á má gbà láàyè kí ó ṣẹlẹ̀. Èrò pé nnkan kò tọ̀nà yí gbilẹ̀ lọ́kàn wa. A mọ oró ìlara èyí tí ó ńmú wa ké nínú wa pé, "Kò tọ̀nà rárá".

Òótọ́ sì ni. Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ gbòógì tí mo ti kọ́ ni pé ìjọba Ọlọ́run kò nífẹ̀ sí kí nnkan wà ní ọgbọọgba. Ọlọ́run lòdì sí kí nnkan wà ní ọgbọọgba.

Mo kọ́kọ́ mọ èyí nígbà tí mo ka òwe Jésù nípa àwon òṣìṣẹ́ nínú ọ̀gbà àjàrà ní Matiu 20. Onílẹ̀ kan gba àwọn òṣìṣẹ́ ó sì ṣe àdéhùn láti san denáríù kan fún wọn fún iṣẹ́ ọjọ́ kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láàrin ọjọ́ yì, onílẹ̀ yì jáde lọ wá àwọn òṣìsẹ́ síi, oníkálùkù sì gbà láti gba dénáríù kan gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yá. Ní àṣálẹ́ tí oníkálùkù wá gba owó iṣẹ́ rẹ̀, àwọn tí a kọ́kọ́ gbà ń retí kí àwọn gba owó ju àwọn tó ṣiṣẹ́ fún wákàtí mẹ́ta péré lọ

Nígbà tí mo ka ìtàn yí, èmi náà rò pé bí ó ṣe tọ̀nà nìyẹn. Ohun tó kọ́kọ́ ta mí jí nínú ìtàn yìí ni èsì tí onílẹ̀ fún àwọn tí ó ń kùn nípa àìtọ̀nà yí. “Ṣé n kò lẹ́tọ̀ láti ṣe ohun tó wù mí pẹ̀lú owó mi ni? Ṣé nítorí pé mo ya'wọ́ lẹ ṣe n ṣé ìlara?” 

Ọlọ́run kò s'ẹ̀tọ́. Kìí fún ni ní ẹ̀bùn, tálẹ́ntì, tàbí ìbùkún ni ọgbọọgba. Kò yé mi bí ó ṣe rí báyìí, ṣùgbọ́n ohun kan tó dá mi lójú ni pé: Ọlọ́run kìí ṣe ẹ̀tọ́, ṣùgbọ́n onínúrere ni. 

Nínú ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Rẹ̀, O fi ara rẹ̀ fún wa, ó di ènìyàn, ó sì ń gbé láàrin wa. Ó dojú kọ gbogbo ìdánwò tí àwa náà ń dojú kọ ṣùgbọ́n kò dẹ́ṣẹ̀. Lẹ́hìn yí ló wá fara da ìjìyà tó burú jù àti ikú oró dípò wa. Dájúdájú, kò ṣohun tó tọ̀nà. Tó bá ṣe é ni, gbogbo wa pátá ni a ó gba ìdájọ́ ọ̀run àpáàdì. 

Kò tọ̀nà, mo sì dúpẹ́ gan an pé kò tọ̀nà.

Àmọ́, ipò tí ọkàn wá wà nípa ìlara jẹ Ẹ́ lógún. Ó fẹ́ kí á di òmìnira lọ́wọ́ àwọn ìmọ̀lára tí ó ń fà wá sẹ́yìn kúrò nínú ọ̀pọ̀ ìbùkún Rẹ̀. 

Gẹ́gẹ́ bí C.S. Lewis ṣe kọ ọ́ nínú ìwé ìtàn àròsọ rẹ̀ The Screwtape Letters “{Ọlọ́run} fẹ́ mú ọ̀kàn ènìyàn wá sí ipò tí yóò leè pèrò Kàtídírà tó dára jùlọ láyé, yóò mọ̀ pé kò lẹ́gbẹ́, yóò sì yọ̀ nínú ìmọ̀ yí, ìdùnnú rẹ̀ kò sì ní yàtọ̀ tó bá tìlẹ̀ jẹ pé ẹlòmíràn ló pèrò rẹ̀. Nígbẹ̀yìn {Ọlọ́run} fẹ́ kí ó láyọ̀ kí ó sì wà láì ṣe ojúsàájú sí ara rẹ́ ṣùgbọ́n, kí ó lè yọ̀ fún tálẹ́ńtì tí ó ní lòtítọ́ àti pẹ̀lú kí ó kún fún ọpẹ́ pé ẹlòmíràn náà ní tálẹ́ńtì - bí yóò ṣe dunnú nígbà t'ó bá rí ìlà òòrùn, erin tàbí omi t'ó ń ṣàn látòkè wá. ” 

Gẹ́gẹ́ bíi ìtànṣán ògo Ọlọ́run, a lee yọ̀ nígbà tí a bá rí ogo yìí, yálà nínú ìṣẹ̀dá tàbí nínú tálẹ́ntì àti ìbùkún nínú ayé àwọn mìíràn. Tí ó bá jẹ́ pé gbogbo nnkan wà fún Un, tí ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ wá, nígbà tí a bá ṣe alábàápàdé ohunkohun tó lè mú kí ẹ̀ran ara wa fẹ́ ṣe ìlara kíkorò, a lè kọ́ ẹ̀mí wa láti kún fún ọpẹ́ fún inú rere Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ ẹlòmíràn ló ń jẹ ànfààní ojú rere ọ̀hún.

Láti borí ìlara, a ní láti ní ọkàn ìmọrírì àti ìmoore. Ọ̀kan lára ọ̀nà tí ó dára jù tí a fi lè ṣe èyí ni kí a súre fún ohun tí a ń ṣe ìlara rẹ̀. Ròyìn ògo àìlẹ́gbẹ́ ohun tí o rí nínú ẹlòmíràn dípò kí o ṣe ìlara rẹ̀. Gbà mí gbọ́, bóyá ó tilẹ̀ yẹ kí wọ́n gbọ́ ìròyìn ògo yì. Sísọ ọ̀rọ̀ ìyè máa ń já agbára tí ìlara ní lórí ọkàn rẹ, á sì yíi padà sí nnkan tí ó yẹ kó jẹ́: ọpẹ́ fún inú rere Ọlọ́run. Gbìdánwò láti máa yọ̀ fún àwọn tí ó ń yọ̀ kí o sì gbàdúrà fún àṣeyọrí àwọn ẹlòmíràn. 

Ìmoore yóò tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìlara. Nígbà tí ó bá yé wa bí Ọlọ́run kò ṣe tọ̀nà tó, a lè mú ọkàn eléèérí wa wá sí inú apá ìfẹ́ Rẹ̀, kí á sì fọkànbalẹ̀ sọ jẹ́ẹ́jẹ́ pé, “O ṣeun Jésù.”

Fún àwọn ohun èlò míràn láti tú ọ sílẹ̀, tẹ̀lé @annalight09 lórí Instagram tàbí lórí www.livelaughlight.com 

Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Break Free From Envy a Six-Day Reading Plan by Anna Light

Ní àkókò yí, ǹkan tó dára nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní wọ́n fihàn fún wa láti rí, àti wípé àfiwé tí a bá ṣe pẹ̀lú ayé tiwa a máa mú owú jẹyọ. O kò fẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa jọba nínú ayé rẹ, àmọ́ kí ló máa ṣe sí àwọn ìjàmbá tó lè wá nípasẹ̀ owú látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn sí ọ? Nínú ètò kíkà yí, o máa rí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà borí owú, pa ọkàn rẹ mọ́, pẹ̀lú òmìnira.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Anna Light (LiveLaughLight) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ lọ sí: http://www.livelaughlight.com