Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jùÀpẹrẹ

Six Steps To Your Best Leadership

Ọjọ́ 7 nínú 7

Bẹ̀rẹ̀ Nísinsìnyí

Máṣe parí ètò Bíbélì yìí láì gbé ìgbésẹ̀ kan pàtó nípa rẹ̀. Àwọn adarí máa ń gbé ìgbẹ́sẹ̀ lórí àlàyé tí máa ń mú ìyípadà wá. Kíni ìṣísẹ̀ náà pàtó tí o nílò láti gbé báyìí? Ọlọ́run ṣe tán láti ṣe ju bí o ti lè bèrè, gbàá rò, tàbí fojú inú wò ó, nípasẹ̀ agbára Rẹ̀ tó wà lójú iṣẹ́.

  1. Ìséra-ẹni láti lè Bẹ̀rẹ̀: Níwọ̀n ìgbà tí o bá mọ ẹni tí ìwọ íṣe, tàbí irúfẹ́ ènìyàn tí o fẹ́ dà, yóò rọrùn fún ọ láti mọ ǹkan tí o nílò láti ṣe. Pẹ̀lú àfojúsùn irúfẹ́ èèyàn tí o fẹ́ dà, irú ìséra wo lo nílò láti bẹ̀rẹ̀? 
  2. Ìgboyà láti Kó Ara Ẹni ní Ìjánu:Pẹ̀lú àfojúsùn irúfẹ́ èèyàn tí o fẹ́ dà, kíni ǹkan náà tí o nílò láti fòpin sí? Má fi ìdiwọ̀n sórí àwọn ǹkan àìda nìkan. Óṣeéṣe kí o nílò láti fòpin sí ohun kan tó ṣe pàtàkì kí o sì gbe fún ẹlòmíràn láti ṣe.
  3. Ẹni tí O lè ró Lágbára: Tani ìwọ yóò ró lágbára? Máṣe jẹ́ ìdíwọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn tí ò ń darí. O tilẹ̀ lè ró ẹnìkan lágbára láti ṣe ǹkan pàtàkì tí ìwọ nílò láti patì pẹ̀lú ìgboyà.
  4. Ètò tí O lè Ṣẹ̀dá: Níbo ni àìbalẹ̀ ọkàn ti ń wáyé? Ibo ni wàhálà ibiṣẹ́ ti ń wáyé? Ètò wo lo nílò láti gbé kalẹ̀ fún àbájáde èsì tó tẹ́nì lọ́run?
  5. Ìbáṣepọ̀ tí O Nílò láti Bẹ̀rẹ̀: Pẹ̀lú àfojúsùn irúfẹ́ èèyàn tí o fẹ́ dà, tani o nílò láti pàdé? Ìbáṣepọ̀ wo lo nílò láti bẹ̀rẹ̀? Ó lè jẹ́ ìbáṣepọ̀ kan tí o kò tíì bẹ̀rẹ̀ ló ń dá ìyípadà kádàrá rẹ ní rere dúró.
  6. Ewu Kan tí O ní Láti Kojú: Pẹ̀lú àfojúsùn irúfẹ́ èèyàn tí o fẹ́ dà àti ǹkan tí o fẹ́ gbé ṣe, kíni ewu tí o nílò láti kojú? Bí o bá ń dúró de àkókò tí ó tọ́ ní gbogbo ìgbà, àti ṣe àṣeyọrí yóò nira fún ọ. 

Lákòótán, jẹ́ ohun tí Ọlọ́run dá ọ láti jẹ́. Yóò rọrùn fún àwọn ènìyàn láti tẹ̀lé adarí tí kìí fi ìkùnà rẹ̀ pamọ́ ju èyí tí ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní gbogbo ìgbà. 

Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀: Ọlọ́run, mo jẹ́rìí Rẹ láti ṣe ju bí ipá ti lè gbé mi lọ. Ǹjẹ́ ìwọ yóò fún mi ní ọgbọ̀n, ìgboyà, àti ipá láti gbé ìṣísẹ̀ tó kàn bí?

Ṣe àyẹ̀wò àwọn ìwàásù mi lórí ìhùwàsí láti lè tẹ̀síwájú síi.

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Six Steps To Your Best Leadership

Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/