Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jùÀpẹrẹ
Ìbáṣepọ̀ Tí O Nílò Láti Bẹ̀rẹ̀
A tẹ́ pẹpẹ ètò Bíbélì yìí nípa fífi ènìyàn náà ṣáájú ojúṣe nì. Bí o bá fẹ́ mú ìyípadà bá irú ènìyàn tí o jẹ́, o máa ní láti mú ìyípadà bá àwọn tí ò ń bá tò.
Pọ́ọ̀lù Àpọ́sítélì, ẹni tí ó ṣe àkọsílẹ̀ èyí tí ó jù nínú Májẹ̀mú Titun, ló ní ìrírí ìyípadà ìgbésí ayé tó yani lẹ́nu jù nínú Bíbélì. Ìyípadà ayée rẹ̀ nípọn débi tí orúkọ rẹ̀ ní àtúntò láti Saulu sí Pọ́ọ̀lù.
Saulu kórìíra àwọn Kristẹni ó sì wù ú láti rí wọn ní pípa. Pọ́ọ̀lù nídàkejì fẹ́ràn àwọn Kristẹni ní gbogbo ọjọ́ ayée rẹ̀. Saulu kẹ́gàn àwọn ọmọ lẹ́yìn Jésù ó sì ń lépa wọn. Pọ́ọ̀lù bá Jésù pàdé lọ́nà ó sì ń lépa láti jíhìn rere rẹ̀. Saulu lo àkókò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn pẹ̀lú ìgbìyànjú láti tẹ̀ Ọlọ́run lọrùn nípa iṣẹ́ ipá. Pọ́ọ̀lù lo àkókò tirẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó ti jọ̀wọ́ ayée wọn, pẹ̀lú ìfarabalẹ̀ fún Ọlọ́run láti ṣiṣẹ́ nínú ayée rẹ̀.
Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù pàdé Jésù ẹni tí ó fi ìmọ́lẹ̀ hàn síi. Lẹ́yìn èyí ló pàdé Ananíà tí ó ṣe ìrànwọ́ fún-un láti ní okun titun àti láti ríran (lójú ko ojú). Lẹ́yìn èyí ló pàdé Bánábà, tí ó ti Pọ́ọ̀lù lẹ́yìn tó sì fi hàn fún àwọn adarí ìjọ nígbà tí ẹrú rẹ̀ ṣì ń bà wọn. Àwọn tí ó pàdé bẹ́ẹ̀ pọ, paríparí rẹ wípé Pọ́ọ̀lù wá di ọ̀kan lára àwọn adarí tí ó yanjú nínú ìtàn.
Bíi Pọ́ọ̀lù, ó lè jẹ́ ìbáṣepọ̀ kan ṣoṣo ló ńṣe ìdíwọ́ fún ìyípadà ipa kádàrá rẹ. Tó bá dé ipele lílo àkókò rẹ pẹ̀lú àwọn mìíràn, má kù gìrì láti dá ẹnikẹ́ni tó bá bèrè lóhùn. Lo àkókò rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó lè mú ọ nà, tó máa tì ọ́ síwájú, tó máa mú àròjinlẹ̀ bá ọ.
Ṣe bíi Pọ́ọ̀lù kí o sì bá ẹnìkan tí o kò gba tirẹ̀ lọ títí pàdé. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ma ń ṣe ìdájọ́ ǹkan tí ó kọjá òye wa. Má kàn kọ́ọ̀wọ́ rìn pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ, àwọn tí ẹ jọ wà ní ipele ìmọ̀ kan náà, tàbí ìrírí kan náà nìkan. Ṣé o ti bọ́ há? Ṣàwárí ẹnìkan tí ó jù ọ́ lọ. Tí ìwọ bá jẹ́ ọmọ ọgbọ́n ọdún, tọ ènìyàn ogójì ọdún lọ kí o sì bèrè ìyàtọ̀ ìrísí wọn nísinsìnyí ní àfiwé ìgbà tí wọ́n wà l'ọ́mọ ọgbọ́n ọdún.
Tọ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ìgbáradì láti tẹ́tí lélẹ̀, bèrè ìbéèrè tó fakọyọ, kí o sì tẹ̀lé àwọn àpẹẹrẹ wọn tó dára. Má kàn jí ìṣe àwọn mìíràn wò, ṣùgbọ́n kọ́ bí wọ́n ti ń ronú.
Lákòótán, tí o kò bá tíì bẹ̀rẹ̀ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jésù, ó ṣeé ṣe kí ìbáṣepọ̀ kan tí o kò ní yìí dí ìyípadà kádàrá rẹ lọ́wọ́. Ayé mi jẹ́ àpẹẹrẹ irú ìyípadà tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí. Ibi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó kẹ́yìn nínú ètò tòní ni àpèjúwe tí Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nípa bí ìbáṣepọ̀ náà yóò ti rí.
Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀: Ọlọ́run, O mọ irú ènìyàn tí o dá mi láti dà jẹ́. Ǹjẹ́ O lè ràn mí lọ́wọ́ láti mọ ẹni tí mo nílò láti tọ̀ lọ? Fún mi ní ọgbọ́n àti ipá láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìbáṣepọ̀ tí ó yẹ.
Jẹ́ kí a mọ̀ tí o bá ti pinu láti bẹ̀rẹ̀ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jésù .
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.
More