Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jùÀpẹrẹ
Ewu Tí O Ní Láti Kojú
Bóyá ọ̀dọ́ lo jẹ́, tàbí o wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, o ti ń ṣiṣẹ́, àbí ìwọ ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, àkókò tí ó pé fún ọ láti ṣe ǹkan tó lè mú ewu dání nìyí. Bí o ti ń dàgbà tàbí lẹ́yìn tí o bá dàgbà tán má fàṣẹ́yìn láti kojú ewu. Kò sí ènìyàn náà tó gbé ǹkan tó jojú ṣe láì kojú ewu.
Èyí kò túmọ̀ sí ṣíṣe àyà gbàǹgbà nídìí àwọn ǹkan tí kò dára. Máṣe fi àwọn ìbárẹ́ rere sínú ewu, máṣe fi ìléra rẹ sínú ewu, má sì ba ohun tó ń lọ ní ìrọ́wọ́-rọsẹ̀ jẹ́. Ṣùgbọ́n, kíni àlàyé tí ìwọ ń tẹ̀lé? Kíni ìtọ́ni tó ń darí rẹ? Kíni àwọn ìwúrí tó múlẹ̀ lọ́kàn rẹ? Fi ara rẹ sínú ewu pẹ̀lú ìgbàgbọ́.
Mo fẹ́ràn ohun tí ààrẹ ànọ́ fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Jimmy Carter sọ, “Lọsí téńté ẹ̀ka igi, ibẹ̀ ni èso wà.”
Bóyá o ti gbọ́ nípa oníṣòwò ọlọ́rọ̀ àti aláìṣòótọ́ nì nínú Bíbélì tó gun ẹ̀ka igi láti kófìrí Jésù. Ìlúmọ̀ọ́ká ló jẹ́ gẹ́gẹ́bí olórí àwọn agbowó-òde, àti wípé ìdí iṣẹ́ yìí ló ti kó ọrọ̀ jọ. Lọ́jọ́ kan ó pa òkìkí rẹ tì láti pọ́n igi lọ, ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti rí Jésù. Jésù rí Sákéhù, ó pèé sọ̀kalẹ̀ láti nìṣó nílé rẹ̀, bí ìgbà tí ayéè rẹ̀ bá yí padà lójijì sí rere ló ti rí.
Bí o bá fẹ́ wà bí o ti wà látẹ̀yìn wá, tẹ̀síwájú nínú ǹkan àtijọ́. Bí o bá fẹ́ yí ìrísí rẹ padà, o ní láti ṣe àtúntò ìṣeè rẹ. Lọ́rọ̀ kan, bí o báma yí èso ayéè rẹ padà, o ní láti fi araà rẹ sínú ewu.
Ṣé ìwé ni ìwọ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ, bóyá o nílò láti kọnu ìfẹ́ sí èèyàn kan, bẹ̀rẹ̀ okòwò, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìránṣẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ sí ilé-ìjọsìn, bẹ̀rẹ̀ ètò orí afẹ́fẹ́, tàbí ǹkan mìíràn? Pẹ̀lú àfojúsùn ǹkan tí Ọlọ́run ń darí rẹ láti ṣe, kíni ewu tí o nílò láti kojú?
Ìgbẹ́sẹ̀: Fi ọ̀rọ̀ lọ ẹnìkan tí o jẹ́rìí nípa ǹkan tí o fẹ́ dáwọ́lé. Lẹ́yìn èyí, gbé ìṣísẹ̀ àkọ́kọ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.
More