Lílò Àkókò Rẹ Fún ỌlọrunÀpẹrẹ
Ríra Ìgbà Rẹ Padà
Àkókò ni amúnidọ́gba ńlá. Òhun ni ǹkan ìní kan tí a pín fún gbogbo ènìyàn ní ọgbọgba. Gbogbo ẹ̀dá alààyè ló ní iye wákàtí kan náà láti lò ní òòjọ́. Kò sí wípé à ń fún àwọn tó níṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe ní wákàtí díẹ̀ si kún tilẹ̀. Ago kìí ṣe ojúsàájú.
Òṣùwọ̀n àkókò kan náà ni gbogbo láǹfààní sí ní òòjọ́. Ibi tí a ti yàtọ̀ síra ni ọ̀nà tí oníkálukú ń gbà ra ìgbà tí a ti fún wọn padà. Nígbà tí a bá ra ǹkan padà, ní ṣeni a gbà á sílẹ̀ tàbí rà á kúrò nínú ipò tí kò dára kan. Ipò kan tí kò dára tí a fẹ́ pe àkíyèsí wa sí ní ìlòkulò. Lílo àkókò ní ìlòkulò túmọ̀ sí lílòó fún ǹkan tí kò níye lórí.
Olóògbé nì Vince Lombardi ló sọ òwe yìí di ìlúmọ̀ọ́ká, "n kò pàdánù rí nínú ayò; àkókò ni kò kàn tó." Àlàyé ló wá tọ́ka mi sí àmúyẹ eré-ìje tó ṣe pàtàkì jù—ìtaraka láti ṣáájú ago. Ẹgbẹ́ tóbá parí ìlépa wọn ní àkókò tó kéré jùlọ ni yóò gbégbá orókè. Nínú eré-ìje, ní àfiwé pẹ̀lú ojú-ayé, àǹfààní wà láti tọrọ gáfárà. A lè dá ago tí a ń lò fún eré-ìje dúró fún ìgbà díẹ̀. Àmọ́ lójú-ayé, kò sí àyè fún gáfárà.
Coram Deo: Wíwà ní sàkání Ọlọ́run
Bèrè kí Ọlọ́run fi àwọn ǹkan tó ń fi àkókò rẹ ṣòfò hàn àti àwọn ọ̀nà tí o lè gbà ra ìgbà padà.
Copyright © Ligonier Ministries. Lo àǹfààní yìí láti rí ìwé ọ̀fẹ́ gbà lọ́wọ́ R.C. Sproul ní Ligonier.org/freeresource.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ẹkọ bíbélì ọlọjọ merin lati ọwọ R.C. Sproul lórí lílo àkókò wà fún Ọlọrun. Ẹkọ bíbélì ikankàn npè wà láti máa gbé ní iwájú Ọlọrun, labẹ aṣẹ Ọlọrun, sí ògo Ọlọrun.
More