Lílò Àkókò Rẹ Fún ỌlọrunÀpẹrẹ

Using Your Time for God

Ọjọ́ 4 nínú 4

Ṣíṣe Ètò Ìlànà Iṣẹ́ Rẹ

Máa lo àsìkò afẹ́ rẹ fún àwọn ìlépa tí ń bu iyì kún ayé ènìyàn. Ìwé kíkà jẹ́ ọ̀nà àìdíyelé tí a lè gbà lo àkókò wa. Nígbà kan rí, Augustine gba àwọn onígbàgbọ níyànjú pé kí wọ́n kọ́ ohun gbogbo tí wón leè kọ́ bí ó ti wù kó pọ̀ tó, nítorí pé gbogbo òdodo jẹ́ tí Ọlọ́run. Àwọn iṣẹ́ ìgbafẹ́ míràn tí ó lè bù iyì kún ènìyàn wà nínú iṣẹ́ ọnà. Mo tún máa ń gbádùn láti fi ìró ohùn s'eré kí nbáa lè jẹ́ kí ìwòyeè mi gbóòrò síi nínú ṣíṣe àmúlò ọ̀rọ̀.

Wá ọ̀nà láti tayọ ara erùpẹ̀. Ìṣeè mi ni láti wọ ìyẹ̀wù láàrin aago mẹ́jọ sí mẹ́sàán alẹ́ bí ó ṣeé ṣe, kí n sì dìde jí ní aago merin òwúrọ̀. Èyí a máa kó' pa ribiribi nínú ìlànà ètò iṣé tí mo bá ní láti ṣe. Kìí sí ìdíwọ́ tàbí ìdánilọ́wọ́kọ́ ní gbogbo wákàtí tó wà l'áààjìn. Àsìkò yìí sì dára làti ṣe àṣàrò ẹ̀kọ́, kọ ìwé àpilẹ̀kọ ati láti gbàdúrà.

Lo àsìkò tí o bá ń wa ọkọ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́. Wíwa ọkọ̀ jẹ́ ohun tí a lè ṣe geerege láì ronú lọ títí, èyí yíò jẹ́ kí ọkàn jáfáfá láti kíyèsi ohun tí ó n lọ ní òpópó-ọ̀nà. A lè lo àsìkò yìí láti fetísí fọ́nrán ìgbohùnsílẹ̀ lórí ẹ̀rọ rédíò inu ọkọ̀.

Lákòtán, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ìlànà ètò iṣẹ́ a máa fi ààyè gbani láì há ẹni mọ́ gágá. Lílo ètò ìlànà iṣẹ́ a máa rannilọ́wọ́ púpọ̀ láti ṣe àmúlò àsìkò wà dáadáa. Ọ̀rẹ́ ni ètò ìlànà iṣẹ́ jẹ́ fún wa kìí ṣe ọ̀tá. A máa jẹ́ kí á mọ bí a ó ṣe gbé ìgbé ayé tó lapa rere tí ó sì f'ogo f'Ọ́lọ́run.

Coram Deo: Gbígbé ninu Ọlọ́run

Bí o kò bà ní ètò ìlànà iṣẹ́, se àgbékalẹ́ ọ̀kan kí o sì lòó fún èyí tí ó kù kí ọ̀sẹ̀ yìí parí, lẹ́hìn èyí, ṣe ìgbéléwọ̀n bí ó ṣé ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ra àsìkò rẹ padà. Tí o bá sì ti ní ètò ìlànà iṣẹ́ tẹ́lẹ, ṣe àtúnyẹwò rẹ̀ kí ọ sì gbàdúrà lórí àwọn ohun tí ọ ṣe pàtàkì jùlọ sí ọ.

Copyright © Ligonier Ministries. Gba ìwé R.C. Sproul kan l'ọ́fẹ̀ẹ́ ní Ligonier.org/freeresource.

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Using Your Time for God

Ẹkọ bíbélì ọlọjọ merin lati ọwọ R.C. Sproul lórí lílo àkókò wà fún Ọlọrun. Ẹkọ bíbélì ikankàn npè wà láti máa gbé ní iwájú Ọlọrun, labẹ aṣẹ Ọlọrun, sí ògo Ọlọrun.

More

A fẹ lati dupẹ lọwọ Ligonier Ministries fun ìpèsè ètò yìí. Fún aláayè lẹkunrẹrẹ, jọwọ lọsi Ligonier.org/youversion