Lílò Àkókò Rẹ Fún ỌlọrunÀpẹrẹ
Jáfáfá ju Ọwọ́ Aago lọ
Mo ti kọ́ àwọn ọgbọ́n inú díẹ̀ tí ó máa ńjẹ́ kí nlè jáfáfá ju ọwọ́ aago lọ. Àwọn ọgbọ́n inú yìí sì lè ṣ'àǹfààní fún ìwọ náà.
Mo ríi mọ̀ dájú pé gbogbo àsìkò mi ti Ọlọ́run ni àtì pé Ọlọ́run gan an l'ó fi gbogbo àsìkò tí mo ní fún mi. Ọlọ́run ló ni mí àti gbogbo àsìkò mi. Síbẹ̀, Ó fi mí ṣe ìríjú àwọn àsìkò díẹ̀ t'ó fún mi. Mo lè lò nínú àsìkò yìí láti ṣiṣẹ́ sìn ẹlòmíràn, ṣe àbẹwò sí àwọn ẹlòmíràn, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ mo níláti jíyìn bí mo ti ṣe lo àwọn àsìkò náà.
A lè rà ìgbà padà nípa ní ní ìfọkànsí àti àfojúsùn. Ọ̀kan nínú àwọn àdánù tí ó ga jùlọ máa ń w'áyé nínú ọkàn ènìyàn. Ọwọ́ wa lè máa ṣ'iṣẹ́, àmọ́ kí ọkàn wa gb'ófo. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀, ọwọ́ wa lè má rí'ṣẹ́ ṣe, kí ọkàn wa sì kún fún oríṣìíríṣìí èrò. Èròkerò, ìrònú asán, àti àwọn àlá òfégè tí kò l'ésènlẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tí èrò ọkàn ńgbà fi àsìkò ṣ'òfò. Tí a bá da'rí ọkàn wa sí iṣé tí a ní láti ṣe - pẹ̀lú ìfọkànsí to gúnmọ́ - ìgbà yìí ni a ó lè lo àsìkò wa fún àbáyọrí gidi.
Ọkàn ènìyàn lè rà ìgbà padà nípa ṣíṣe àmúlò àsìkò tí à ń lò fún àwọn ìṣe ojoojúmọ́. Fún àpẹẹrẹ, bí a ṣe ń wẹ̀ ní balùwẹ̀ kò ni ni lára. N'írú àkókò báyìí, ọkàn á ní ààye fún ṣíṣe àwárí ojútùú sí ìṣòro, ṣíṣ'ẹ̀dá ọgbọ́n àtinúdá, tàbí kí o se àgbékalẹ̀ onírúurú ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwàásù àti ẹ̀kọ́ mi máa ńjẹ jáde lásìkò tí mo bá ńwẹ̀. N'ígbà tí mo ṣì máa ngbà bọ́ọ̀lù àfigigbá dáadáa, mo ríi pé àsìkò tó wà láàrin ìgbà tí yíò kàn mí láti gbá bọ́ọ̀lù témi jẹ́ àsìkò láti ṣe àkójọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwàásù mi nínú ọkàn mi.
Coram Deo: Gbígbé ninu Ọlọ́run
Kíyèsi ibi tí ọ darí ifojúsùn ọkàn rẹ sí lónìí. Tiraka láti ṣe àmúlò àwọn àsìkò tí a fí ńṣe àwọn ǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti ronú àwọn ohun tó ní iye ayérayé lórí.
Copyright © Ligonier Ministries. Get a free book from R.C. Sproul at Ligonier.org/freeresource.
Nípa Ìpèsè yìí
Ẹkọ bíbélì ọlọjọ merin lati ọwọ R.C. Sproul lórí lílo àkókò wà fún Ọlọrun. Ẹkọ bíbélì ikankàn npè wà láti máa gbé ní iwájú Ọlọrun, labẹ aṣẹ Ọlọrun, sí ògo Ọlọrun.
More