O. Daf 93:1-5
O. Daf 93:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA jọba, ọla-nla li o wọ li aṣọ; agbara ni Oluwa wọ̀ li aṣọ, o fi di ara rẹ̀ li amure: o si fi idi aiye mulẹ, ti kì yio fi le yi. Lati igba atijọ li a ti fi idi itẹ́ rẹ kalẹ, ati aiye-raiye ni Iwọ. Iṣan-omi gbé ohùn wọn soke, Oluwa, iṣan-omi gbé ohùn wọn soke; iṣan-omi gbé riru omi wọn soke. Oluwa li ologo, o li ogo jù ariwo omi pupọ lọ, jù riru omi nla, ani jù agbara riru omi okun lọ. Otitọ li ẹri rẹ: ìwa-mimọ́ li o yẹ ile rẹ lailai, Oluwa.
O. Daf 93:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù; OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀, ó sì di agbára ni àmùrè. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì ní yẹ̀ laelae. A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae; láti ayérayé ni o ti wà. Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA, ibú omi gbé ohùn wọn sókè, ó sì ń sán bí ààrá. OLUWA lágbára lókè! Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ, ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ. Àwọn òfin rẹ kìí yipada, ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA.
O. Daf 93:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ; ọláńlá ni OLúWA wọ̀ ní aṣọ àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí. Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayérayé. A ti gbé Òkun sókè, OLúWA, Òkun ti gbé ohùn wọn sókè; Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè. Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju Òkun rírú lọ OLúWA ga ní ògo. Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin; ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, OLúWA.