O. Daf 93

93
Ọlọrun Ọba
1OLUWA jọba, ọla-nla li o wọ li aṣọ; agbara ni Oluwa wọ̀ li aṣọ, o fi di ara rẹ̀ li amure: o si fi idi aiye mulẹ, ti kì yio fi le yi.
2Lati igba atijọ li a ti fi idi itẹ́ rẹ kalẹ, ati aiye-raiye ni Iwọ.
3Iṣan-omi gbé ohùn wọn soke, Oluwa, iṣan-omi gbé ohùn wọn soke; iṣan-omi gbé riru omi wọn soke.
4Oluwa li ologo, o li ogo jù ariwo omi pupọ lọ, jù riru omi nla, ani jù agbara riru omi okun lọ.
5Otitọ li ẹri rẹ: ìwa-mimọ́ li o yẹ ile rẹ lailai, Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 93: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀