O. Daf 86:1-17

O. Daf 86:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA, dẹ eti rẹ silẹ, gbohùn mi: nitori ti emi jẹ́ talaka ati alaini. Pa ọkàn mi mọ́; nitori emi li ẹniti iwọ ṣe ojurere fun: iwọ, Ọlọrun mi, gbà ọmọ ọdọ rẹ ti o gbẹkẹle ọ. Ṣãnu fun mi, Oluwa: nitori iwọ li emi nkepè lojojumọ. Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ. Oluwa, fi eti si adura mi; ki o si fiye si ohùn ẹ̀bẹ mi. Li ọjọ ipọnju mi, emi o kepè ọ: nitori ti iwọ o da mi lohùn. Oluwa, ninu awọn oriṣa kò si ọ̀kan ti o dabi rẹ, bẹ̃ni kò si iṣẹ kan ti o dabi iṣẹ rẹ. Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ. Nitoripe iwọ pọ̀, iwọ si nṣe ohun iyanu: iwọ nikan li Ọlọrun. Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ. Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai. Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin. Ọlọrun, awọn agberaga dide si mi, ati ijọ awọn alagbara nwá ọkàn mi kiri; nwọn kò si fi ọ pè li oju wọn. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li Ọlọrun ti o kún fun iyọ́nu, ati olore-ọfẹ, olupamọra, o si pọ̀ li ãnu ati otitọ. Yipada si mi ki o si ṣãnu fun mi; fi ipá rẹ fun iranṣẹ rẹ, ki o si gbà ọmọkunrin iranṣẹ-birin rẹ là. Fi àmi hàn mi fun rere; ki awọn ti o korira mi ki o le ri i, ki oju ki o le tì wọn, nitori iwọ, Oluwa, li o ti ràn mi lọwọ ti o si tù mi ninu.

O. Daf 86:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi, nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí. Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí; gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là; ìwọ ni Ọlọrun mi. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru. Mú inú iranṣẹ rẹ dùn, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA, o máa ń dárí jini; ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́. Fetí sí adura mi, OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́, nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi. OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa; kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá, OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ: wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo. Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọrun. OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ; kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ. Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi; n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi; o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú. Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi; ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi; wọn kò sì bìkítà fún ọ. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore; o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́. Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi; fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ; kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là. Fi àmì ojurere rẹ hàn mí, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n; nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́, tí o sì tù mí ninu.

O. Daf 86:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbọ́, OLúWA, kí o sì dá mi lóhùn, nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní. Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ: ìwọ ni Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. Ṣàánú fún mi, OLúWA, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́. Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ, OLúWA, ni mo gbé ọkàn mí sókè sí. Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, OLúWA, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́, Gbọ́ àdúrà mi, OLúWA; tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn. Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, OLúWA: kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, OLúWA; wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀. Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọ́run. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLúWA, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ. Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú. Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè. Ṣùgbọ́n ìwọ, OLúWA, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́. Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là. Fi ààmì hàn mí fún rere, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri, kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ OLúWA ni ó ti tù mí nínú.