O. Daf 86

86
Adura Ìrànlọ́wọ́
1OLUWA, dẹ eti rẹ silẹ, gbohùn mi: nitori ti emi jẹ́ talaka ati alaini.
2Pa ọkàn mi mọ́; nitori emi li ẹniti iwọ ṣe ojurere fun: iwọ, Ọlọrun mi, gbà ọmọ ọdọ rẹ ti o gbẹkẹle ọ.
3Ṣãnu fun mi, Oluwa: nitori iwọ li emi nkepè lojojumọ.
4Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si.
5Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ.
6Oluwa, fi eti si adura mi; ki o si fiye si ohùn ẹ̀bẹ mi.
7Li ọjọ ipọnju mi, emi o kepè ọ: nitori ti iwọ o da mi lohùn.
8Oluwa, ninu awọn oriṣa kò si ọ̀kan ti o dabi rẹ, bẹ̃ni kò si iṣẹ kan ti o dabi iṣẹ rẹ.
9Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ.
10Nitoripe iwọ pọ̀, iwọ si nṣe ohun iyanu: iwọ nikan li Ọlọrun.
11Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ.
12Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai.
13Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin.
14Ọlọrun, awọn agberaga dide si mi, ati ijọ awọn alagbara nwá ọkàn mi kiri; nwọn kò si fi ọ pè li oju wọn.
15Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li Ọlọrun ti o kún fun iyọ́nu, ati olore-ọfẹ, olupamọra, o si pọ̀ li ãnu ati otitọ.
16Yipada si mi ki o si ṣãnu fun mi; fi ipá rẹ fun iranṣẹ rẹ, ki o si gbà ọmọkunrin iranṣẹ-birin rẹ là.
17Fi àmi hàn mi fun rere; ki awọn ti o korira mi ki o le ri i, ki oju ki o le tì wọn, nitori iwọ, Oluwa, li o ti ràn mi lọwọ ti o si tù mi ninu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 86: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀