ORIN DAFIDI 86

86
Adura Ìrànlọ́wọ́
1Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi,
nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí.
2Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí;
gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là;
ìwọ ni Ọlọrun mi.
3Ṣàánú mi, OLUWA,
nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru.
4Mú inú iranṣẹ rẹ dùn,
nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.
5Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA,
o máa ń dárí jini;
ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.
6Fetí sí adura mi, OLUWA,
gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi.
7Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́,
nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi.
8OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa;
kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ.
9Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá,
OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ:
wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo.
10Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;
ìwọ nìkan ni Ọlọrun.#Ifi 15:4
11OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,
kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;
kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;
n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.
13Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;
o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú.
14Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;
ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;
wọn kò sì bìkítà fún ọ.
15Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;
o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.
16Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;
fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;
kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là.
17Fi àmì ojurere rẹ hàn mí,
kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i,
kí ojú sì tì wọ́n;
nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́,
tí o sì tù mí ninu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 86: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀