O. Daf 67:1-7
O. Daf 67:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
KI Ọlọrun ki o ṣãnu fun wa, ki o si busi i fun wa; ki o si ṣe oju rẹ̀ ki o mọlẹ si wa lara, Ki ọ̀na rẹ ki o le di mimọ̀ li aiye, ati igbala ilera rẹ ni gbogbo orilẹ-ède. Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ. Jẹ ki inu awọn orilẹ-ède ki o dùn, ki nwọn ki o ma kọrin fun ayọ̀: nitoriti iwọ o fi ododo ṣe idajọ enia, iwọ o si jọba awọn orilẹ-ède li aiye. Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ. Nigbana ni ilẹ yio to ma mu asunkún rẹ̀ wá; Ọlọrun, Ọlọrun wa tikararẹ̀ yio busi i fun wa. Ọlọrun yio busi i fun wa; ati gbogbo opin aiye yio si ma bẹ̀ru rẹ̀.
O. Daf 67:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Kí Ọlọrun óo ṣàánú wa, kí ó bukun wa; kí ojú rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí wa lára; kí gbogbo ayé lè mọ ọ̀nà rẹ̀; kí gbogbo orílẹ̀-èdè sì mọ ìgbàlà rẹ̀. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun; jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́! Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn, kí wọn ó máa kọrin ayọ̀, nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju; o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun; jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́! Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde; Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa. Ọlọrun bukun wa, kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù rẹ̀.
O. Daf 67:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa, kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká, kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé, ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́! Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn, ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela. Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run, Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa. Ọlọ́run yóò bùkún fún wa, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.