O. Daf 67

67
Orin Ọpẹ́
1KI Ọlọrun ki o ṣãnu fun wa, ki o si busi i fun wa; ki o si ṣe oju rẹ̀ ki o mọlẹ si wa lara,
2Ki ọ̀na rẹ ki o le di mimọ̀ li aiye, ati igbala ilera rẹ ni gbogbo orilẹ-ède.
3Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ.
4Jẹ ki inu awọn orilẹ-ède ki o dùn, ki nwọn ki o ma kọrin fun ayọ̀: nitoriti iwọ o fi ododo ṣe idajọ enia, iwọ o si jọba awọn orilẹ-ède li aiye.
5Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ.
6Nigbana ni ilẹ yio to ma mu asunkún rẹ̀ wá; Ọlọrun, Ọlọrun wa tikararẹ̀ yio busi i fun wa.
7Ọlọrun yio busi i fun wa; ati gbogbo opin aiye yio si ma bẹ̀ru rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 67: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀