O. Daf 68

68
Orin ìṣẹ́gun ti Orílẹ̀-Èdè
1KI Ọlọrun ki o dide, ki a si tú awọn ọta rẹ̀ ka: ki awọn ti o korira rẹ̀ pẹlu, ki nwọn ki o salọ kuro niwaju rẹ̀.
2Bi ẽfin ti ifẹ lọ, bẹ̃ni ki o fẹ́ wọn lọ; bi ida ti iyọ́ niwaju iná, bẹ̃ni ki enia buburu ki o ṣegbe niwaju Ọlọrun.
3Ṣugbọn jẹ ki inu awọn olododo ki o dùn; ki nwọn ki o yọ̀ niwaju Ọlọrun; nitõtọ, ki nwọn ki o yọ̀ gidigidi.
4Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹ kọrin iyin si orukọ rẹ̀: ẹ la ọ̀na fun ẹniti nrekọja li aginju nipa JAH, orukọ rẹ̀, ki ẹ si ma yọ̀ niwaju rẹ̀.
5Baba awọn alainibaba ati onidajọ awọn opó, li Ọlọrun ni ibujoko rẹ̀ mimọ́.
6Ọlọrun mu ẹni-ofo joko ninu ile: o mu awọn ti a dè li ẹ̀wọn jade wá si irọra: ṣugbọn awọn ọlọtẹ ni ngbe inu ilẹ gbigbẹ.
7Ọlọrun, nigbati iwọ jade lọ niwaju awọn enia rẹ, nigbati iwọ nrìn lọ larin aginju.
8Ilẹ mì, ọrun bọ silẹ niwaju Ọlọrun: ani Sinai tikararẹ̀ mì niwaju Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.
9Ọlọrun, iwọ li o rán ọ̀pọlọpọ òjo si ilẹ-ini rẹ, nigbati o rẹ̀ ẹ tan, iwọ tù u lara.
10Ijọ enia rẹ li o tẹ̀do sinu rẹ̀: iwọ Ọlọrun ninu ore rẹ li o ti pèse fun awọn talaka.
11Oluwa ti sọ̀rọ: ọ̀pọlọpọ si li ogun awọn ẹniti nfi ayọ̀ rohin rẹ̀:
12Awọn ọba awọn ẹgbẹ ogun sa, nwọn sa lọ: obinrin ti o si joko ni ile ni npin ikogun na.
13Nigbati ẹnyin dubulẹ larin agbo ẹran, nigbana ni ẹnyin o dabi iyẹ adaba ti a bò ni fadaka, ati ìyẹ́ rẹ̀ pẹlu wura pupa.
14Nigbati Olodumare tú awọn ọba ká ninu rẹ̀, o dabi òjo-didì ni Salmoni.
15Òke Ọlọrun li òke Baṣani: òke ti o ni ori pupọ li òke Baṣani.
16Ẽṣe ti ẹnyin nfi ilara wò, ẹnyin òke, òke na ti Ọlọrun fẹ lati ma gbe? nitõtọ, Oluwa yio ma gbe ibẹ lailai.
17Ainiye ni kẹkẹ́ ogun Ọlọrun, ani ẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun: Oluwa mbẹ larin wọn, ni Sinai ni ibi mimọ́ nì.
18Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe.
19Olubukún li Oluwa, ẹni ti o nba wa gbé ẹrù wa lojojumọ; Ọlọrun ni igbala wa.
20Ẹniti iṣe Ọlọrun wa li Ọlọrun igbala; ati lọwọ Jehofah Oluwa, li amúwa lọwọ ikú wà.
21Nitori Ọlọrun yio fọ ori awọn ọta rẹ̀, ati agbari onirun ti iru ẹniti nrìn sibẹ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
22Oluwa wipe, emi o tun mu pada lati Baṣani wá, emi o tun mu wọn pada lati ibu okun wá.
23Ki ẹsẹ rẹ ki o le pọ́n ninu ẹ̀jẹ awọn ọta rẹ, ati àhọn awọn aja rẹ ninu rẹ̀ na.
24Nwọn ti ri ìrin rẹ, Ọlọrun; ani ìrin Ọlọrun mi, Ọba mi, ninu ibi mimọ́ nì.
25Awọn akọrin lọ niwaju, awọn olohun-elo orin kẹhin; larin awọn ọmọbinrin ti nwọn nlu ìlu.
26Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun li ẹgbẹgbẹ, ani fun Oluwa, ẹnyin ti o ti orisun Israeli wá.
27Nibẹ ni Benjamini kekere wà, pẹlu olori wọn, awọn ọmọ-alade Juda pẹlu awọn igbimọ wọn, awọn ọmọ-alade Sebuloni, ati awọn ọmọ-alade Naftali.
28Ọlọrun rẹ ti paṣẹ agbara rẹ: Ọlọrun fi ẹsẹ eyi ti o ti ṣe fun wa mulẹ.
29Nitori tempili rẹ ni Jerusalemu li awọn ọba yio ma mu ọrẹ fun ọ wá.
30Ba awọn ẹranko ẽsu wi, ọ̀pọlọpọ awọn akọ-malu, pẹlu awọn ọmọ-malu enia, titi olukulùku yio fi foribalẹ pẹlu ìwọn fadaka: tú awọn enia ti nṣe inu didùn si ogun ka.
31Awọn ọmọ-alade yio ti Egipti jade wá; nisisiyi ni Etiopia yio nà ọwọ rẹ̀ si Ọlọrun.
32Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹnyin ijọba aiye; ẹ kọrin iyìn si Oluwa.
33Si ẹniti ngùn ati ọrun de ọrun atijọ; wò o, o fọhùn rẹ̀, eyi na li ohùn nla.
34Ẹ jẹwọ agbara fun Ọlọrun; ọlá-nla rẹ̀ wà lori Israeli, ati agbara rẹ̀ mbẹ li awọsanma.
35Ọlọrun, iwọ li ẹ̀ru lati ibi mimọ́ rẹ wọnni wá: Ọlọrun Israeli li On, ti nfi ilera ati agbara fun awọn enia rẹ̀. Olubukún li Ọlọrun!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 68: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀