O. Daf 66:1-20

O. Daf 66:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ hó iho ayọ̀ si Ọlọrun, ẹnyin ilẹ gbogbo: Ẹ kọrin ọlá orukọ rẹ̀: ẹ mu iyìn rẹ̀ li ogo. Ẹ wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti li ẹ̀ru to ninu iṣẹ rẹ! nipa ọ̀pọ agbara rẹ li awọn ọta rẹ yio fi ori wọn balẹ fun ọ. Gbogbo aiye ni yio ma sìn ọ, nwọn o si ma kọrin si ọ; nwọn o ma kọrin si orukọ rẹ. Ẹ wá wò iṣẹ Ọlọrun, o li ẹ̀ru ni iṣe rẹ̀ si awọn ọmọ enia. O sọ okun di ilẹ gbigbẹ: nwọn fi ẹsẹ là odò já: nibẹ li awa gbe yọ̀ ninu rẹ̀. O jọba nipa agbara rẹ̀ lailai; oju rẹ̀ nwò awọn orilẹ-ède: ki awọn ọlọtẹ ki o máṣe gbé ara wọn ga. Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun wa, ẹnyin enia, ki ẹ si mu ni gbọ́ ohùn iyìn rẹ̀. Ẹniti o mu ẹmi wa wà lãye, ti kò si jẹ ki ẹsẹ wa ki o yẹ̀. Ọlọrun, nitori ti iwọ ti ridi wa: iwọ ti dan wa wò, bi ã ti idan fadaka wò. Iwọ mu wa wọ̀ inu àwọn; iwọ fi ipọnju le wa li ẹgbẹ. Iwọ mu awọn enia gùn wa li ori: awa nwọ inu iná ati omi lọ, ṣugbọn iwọ mu wa jade wá si ibi irọra. Emi o lọ sinu ile rẹ ti emi ti ẹbọ sisun: emi o san ẹjẹ́ mi fun ọ, Ti ète mi ti jẹ́, ti ẹnu si ti sọ, nigbati mo wà ninu ipọnju. Emi o ru ẹbọ sisun ọlọra si ọ, pẹlu õrùn ọrá àgbo; emi o rubọ akọ-malu pẹlu ewurẹ. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, emi o sọ ohun ti o ṣe fun ọkàn mi. Emi fi ẹnu mi kigbe pè e, emi o si fi àhọn mi buyin fun u. Bi emi ba gbà ẹ̀ṣẹ li aiya mi, Oluwa kì yio gbohùn mi: Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun ti gbohùn mi: o si ti fi eti si ohùn adura mi. Olubukún li Ọlọrun, ti kò yi adura mi pada kuro, tabi ãnu rẹ̀ kuro lọdọ mi.

O. Daf 66:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun. Ẹ kọ orin ògo yin orúkọ rẹ̀; ẹ yìn ín, ẹ fògo fún un! Ẹ sọ fún Ọlọrun pé, “Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ, agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ. Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́; wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ, wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe, iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù. Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀, àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò. Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe. Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae. Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji, kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i. Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀; ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè, tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò; o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná. O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n; o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí. O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀, a ti la iná ati omi kọjá; sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú. N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun; n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ. Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́, tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú. N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ, èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run, n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi. Mo ké pè é, mo sì kọrin yìn ín. Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi, OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi. Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́; ó sì ti dáhùn adura mi. Ìyìn ni fún Ọlọrun, nítorí pé kò kọ adura mi; kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi.

O. Daf 66:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo! Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀; Ẹ kọrin ìyìnsí i, Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé, ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ! Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi sìn ọ́. Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ; wọn ń kọrin ìyìn sí ọ, wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela. Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe, Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn! Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀. Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀, ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela. Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn, jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀; Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa, kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀ Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò; ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò. Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀. Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìṣòro. Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ, àti ẹbọ ọ̀rá àgbò; èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela. Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run; ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi. Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i: Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi. Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi; Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà. Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!