Saamu 66:1-20

Saamu 66:1-20 YCB

Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo! Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀; Ẹ kọrin ìyìnsí i, Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé, ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ! Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi sìn ọ́. Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ; wọn ń kọrin ìyìn sí ọ, wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela. Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe, Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn! Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀. Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀, ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela. Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn, jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀; Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa, kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀ Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò; ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò. Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀. Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìṣòro. Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ, àti ẹbọ ọ̀rá àgbò; èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela. Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run; ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi. Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i: Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi. Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi; Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà. Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!