ORIN DAFIDI 66:1-20

ORIN DAFIDI 66:1-20 YCE

Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun. Ẹ kọ orin ògo yin orúkọ rẹ̀; ẹ yìn ín, ẹ fògo fún un! Ẹ sọ fún Ọlọrun pé, “Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ, agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ. Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́; wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ, wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe, iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù. Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀, àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò. Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe. Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae. Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji, kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i. Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀; ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè, tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò; o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná. O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n; o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí. O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀, a ti la iná ati omi kọjá; sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú. N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun; n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ. Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́, tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú. N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ, èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run, n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi. Mo ké pè é, mo sì kọrin yìn ín. Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi, OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi. Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́; ó sì ti dáhùn adura mi. Ìyìn ni fún Ọlọrun, nítorí pé kò kọ adura mi; kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi.