O. Daf 40:1-17

O. Daf 40:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi. O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ. O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa. Ibukún ni fun ọkunrin na ti o fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀, ti kò si ka onirera si, tabi iru awọn ti nyà si iha eke. Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ. Ẹbọ ati ọrẹ iwọ kò fẹ: eti mi ni iwọ ti ṣi: ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ-ẹbọ ẹ̀ṣẹ on ni iwọ kò bère. Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i, emi de: ninu àpo-iwe nì li a gbe kọwe mi pe, Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi. Emi ti wãsu ododo ninu awujọ nla: kiyesi i, emi kò pa ete mi mọ́, Oluwa, iwọ mọ̀. Emi kò fi ododo rẹ sin li aiya mi, emi o sọ̀rọ otitọ ati igbala rẹ: emi kò si pa iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ mọ́ kuro lọdọ ijọ nla nì. Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo. Nitoripe ainiye ibi li o yika kiri: ẹ̀ṣẹ mi dì mọ mi, bẹ̃li emi kò le gbé oju wò oke, nwọn jù irun ori mi lọ: nitorina aiya mi npá mi. Ki o wù ọ, Oluwa, lati gbà mi: Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ, Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si damu pọ̀, awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run; ki a lé wọn pada sẹhin, ki a si dojuti awọn ti nfẹ mi ni ibi. Ki nwọn ki o di ofo fun ère itiju wọn, awọn ti nwi fun mi pe, A! a! Ki gbogbo awọn ti nwá ọ, ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn sipa tirẹ: ki gbogbo awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Gbigbega li Oluwa. Ṣugbọn talaka ati alaini li emi; Oluwa si nṣe iranti mi; iwọ ni iranlọwọ mi ati olugbala mi: máṣe pẹ titi, Ọlọrun mi.

O. Daf 40:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA, ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun, láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀; ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta, ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa. Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà, tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA, tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn, àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa. OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa, o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá. Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ; bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe, kí n máa ròyìn wọn, wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ, ṣugbọn o là mí ní etí; o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé; a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé: mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi; mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.” Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá. Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀. Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́. Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ; n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu àwùjọ ńlá. Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA, sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́. Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká, ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí, tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran. Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, ọkàn mi ti dàrú. OLUWA, dákun gbà mi; yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí mi, kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata, jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn, kí wọ́n sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n, kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú, àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ; kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!” Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí; ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi, má pẹ́, Ọlọrun mi.

O. Daf 40:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de OLúWA; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi. Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà. Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé OLúWA. Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó fi OLúWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn. OLúWA Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe. Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa; ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn, wọ́n ju ohun tí ènìyàn le è kà lọ. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti ṣí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè. Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé. Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi; Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.” Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà láàrín àwùjọ ńlá; wò ó, èmi kò pa ètè mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀, ìwọ OLúWA. Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi; èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ. Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá. Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; OLúWA jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé. Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́; wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà. Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ OLúWA, láti gbà mí là; OLúWA, yára láti ràn mí lọ́wọ́. Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì kí wọn kí ó sì dààmú àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun: jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n, àwọn tí ń wá ìpalára mi. Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!” ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ kí ó máa yọ̀ kí inú wọn sì máa dùn sí ọ; kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ kí o máa wí nígbà gbogbo pé, “Gbígbéga ni OLúWA!” Bí ó ṣe ti èmi ni, tálákà àti aláìní ni èmi, ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti ìgbàlà mi; Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́, ìwọ Ọlọ́run mi.

O. Daf 40:1-17

O. Daf 40:1-17 YBCV