O. Daf 40

40
Orin ìyìn
1NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi.
2O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ.
3O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa.
4Ibukún ni fun ọkunrin na ti o fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀, ti kò si ka onirera si, tabi iru awọn ti nyà si iha eke.
5Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ.
6Ẹbọ ati ọrẹ iwọ kò fẹ: eti mi ni iwọ ti ṣi: ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ-ẹbọ ẹ̀ṣẹ on ni iwọ kò bère.
7Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i, emi de: ninu àpo-iwe nì li a gbe kọwe mi pe,
8Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi.
9Emi ti wãsu ododo ninu awujọ nla: kiyesi i, emi kò pa ete mi mọ́, Oluwa, iwọ mọ̀.
10Emi kò fi ododo rẹ sin li aiya mi, emi o sọ̀rọ otitọ ati igbala rẹ: emi kò si pa iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ mọ́ kuro lọdọ ijọ nla nì.
11Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo.
Adura Ìrànlọ́wọ́
12Nitoripe ainiye ibi li o yika kiri: ẹ̀ṣẹ mi dì mọ mi, bẹ̃li emi kò le gbé oju wò oke, nwọn jù irun ori mi lọ: nitorina aiya mi npá mi.
13Ki o wù ọ, Oluwa, lati gbà mi: Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ,
14Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si damu pọ̀, awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run; ki a lé wọn pada sẹhin, ki a si dojuti awọn ti nfẹ mi ni ibi.
15Ki nwọn ki o di ofo fun ère itiju wọn, awọn ti nwi fun mi pe, A! a!
16Ki gbogbo awọn ti nwá ọ, ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn sipa tirẹ: ki gbogbo awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Gbigbega li Oluwa.
17Ṣugbọn talaka ati alaini li emi; Oluwa si nṣe iranti mi; iwọ ni iranlọwọ mi ati olugbala mi: máṣe pẹ titi, Ọlọrun mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 40: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀