O. Daf 39

39
Ìráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ
1MO ni, emi o ma kiyesi ọ̀na mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣẹ̀; emi o fi ijanu ko ara mi li ẹnu nigbati enia buburu ba mbẹ niwaju mi.
2Mo fi idakẹ yadi, mo tilẹ pa ẹnu mi mọ́ kuro li ọ̀rọ rere: ibinujẹ mi si ru soke.
3Aiya mi gbona ninu mi, nigbati emi nronu, ina ràn: nigbana ni mo fi ahọn mi sọ̀rọ.
4Oluwa, jẹ ki emi ki o mọ̀ opin mi ati ìwọn ọjọ mi, bi o ti ri; ki emi ki o le mọ̀ ìgbà ti mo ni nihin.
5Kiyesi i, iwọ ti sọ ọjọ mi dabi ibu atẹlẹwọ; ọjọ ori mi si dabi asan niwaju rẹ: nitõtọ olukuluku enia ninu ijoko rere rẹ̀ asan ni patapata.
6Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ.
7Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ.
8Gbà mi ninu irekọja mi gbogbo: ki o má si sọ mi di ẹni ẹ̀gan awọn enia buburu.
9Mo yadi, emi kò ya ẹnu mi; nitoripe iwọ li o ṣe e.
10Mu ọwọ ìna rẹ kuro li ara mi: emi ṣegbe tan nipa ìja ọwọ rẹ.
11Nigbati iwọ ba fi ibawi kilọ fun enia nitori ẹ̀ṣẹ, iwọ a ṣe ẹwà rẹ̀ a parun bi kòkoro aṣọ: nitõtọ asan li enia gbogbo.
12Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri.
13Da mi si, ki emi li agbara, ki emi ki o to lọ kuro nihinyi, ati ki emi ki o to ṣe alaisi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 39: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀