O. Daf 38
38
Adura Ẹni tí Ìyà ń Jẹ
1OLUWA, máṣe ba mi wi ninu ibinu rẹ: bẹ̃ni ki o máṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ.
2Nitori ti ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ rẹ si kì mi wọ̀ mọlẹ.
3Kò si ibi yíyè li ara mi nitori ibinu rẹ; bẹ̃ni kò si alafia li egungun mi nitori ẹ̀ṣẹ mi.
4Nitori ti ẹbi ẹ̀ṣẹ mi bori mi mọlẹ, bi ẹrù wuwo, o wuwo jù fun mi.
5Ọgbẹ mi nrùn, o si dibajẹ nitori were mi.
6Emi njowere; ori mi tẹ̀ ba gidigidi; emi nṣọ̀fọ kiri li gbogbo ọjọ.
7Nitoriti iha mi kún fun àrun ẹgbin; kò si si ibi yiyè li ara mi.
8Ara mi hù, o si kan bajẹ; emi ti nkerora nitori aisimi aiya mi.
9Oluwa, gbogbo ifẹ mi mbẹ niwaju rẹ; ikerora mi kò si pamọ́ kuro lọdọ rẹ.
10Aiya mi nmi-hẹlẹ, agbara mi yẹ̀ mi silẹ: bi o ṣe ti imọlẹ oju mi ni, kò si lara mi.
11Awọn olufẹ ati awọn ọrẹ mi duro li òkere kuro ni ìna mi, ati awọn ibatan mi duro li òkere rére.
12Awọn pẹlu ti nwá ọkàn mi dẹkùn silẹ fun mi; ati awọn ti nwá ifarapa mi nsọ̀rọ ohun buburu, nwọn si ngbiro ẹ̀tan li gbogbo ọjọ.
13Ṣugbọn emi, bi aditi, emi kò gbọ́; ati bi odi ti kò ya ẹnu rẹ̀.
14Bẹ̃ni mo dabi ọkunrin ti kò gbọ́ran, ati li ẹnu ẹniti iyàn kò si.
15Nitori, Oluwa, iwọ li emi duro dè, iwọ o gbọ́, Oluwa Ọlọrun mi.
16Nitori ti mo wipe, Gbohùn mi, ki nwọn ki o má ba yọ̀ mi; nigbati ẹsẹ mi ba yọ́, nwọn o ma gbé ara wọn ga si mi.
17Emi ti mura ati ṣubu, ikãnu mi si mbẹ nigbagbogbo niwaju mi.
18Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi.
19Ṣugbọn ara yá awọn ọta mi, ara wọn le; awọn ti o korira mi lodi npọ̀ si i.
20Awọn ti o si nfi buburu san rere li ọta mi; nitori emi ntọpa ohun ti iṣe rere.
21Oluwa, máṣe kọ̀ mi silẹ; Ọlọrun mi, máṣe jina si mi.
22Yara lati ran mi lọwọ, Oluwa igbala mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 38: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.