ORIN DAFIDI 40:1-17

ORIN DAFIDI 40:1-17 YCE

Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA, ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun, láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀; ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta, ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa. Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà, tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA, tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn, àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa. OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa, o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá. Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ; bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe, kí n máa ròyìn wọn, wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ, ṣugbọn o là mí ní etí; o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé; a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé: mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi; mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.” Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá. Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀. Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́. Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ; n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu àwùjọ ńlá. Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA, sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́. Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká, ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí, tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran. Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, ọkàn mi ti dàrú. OLUWA, dákun gbà mi; yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí mi, kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata, jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn, kí wọ́n sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n, kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú, àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ; kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!” Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí; ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi, má pẹ́, Ọlọrun mi.

Verse Image for ORIN DAFIDI 40:1-17

ORIN DAFIDI 40:1-17 - Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA,
ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi.
Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun,
láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀;
ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta,
ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀.
Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,
àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa.
Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,
wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà,
tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA,
tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn,
àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa.
OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa,
o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá.
Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ;
bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe,
kí n máa ròyìn wọn,
wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ.

O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,
ṣugbọn o là mí ní etí;
o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;
a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:
mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;
mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”

Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.
Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀.
Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.
Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;
n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
ninu àwùjọ ńlá.

Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,
sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.

Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,
ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,
tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.
Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
ọkàn mi ti dàrú.
OLUWA, dákun gbà mi;
yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.
Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́
gba ẹ̀mí mi,
kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata,
jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,
kí wọ́n sì tẹ́.
Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n,
kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú,
àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi.

Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀,
kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ;
kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ
máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!”

Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí;
ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi,
má pẹ́, Ọlọrun mi.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ORIN DAFIDI 40:1-17