ORIN DAFIDI 40

40
Orin ìyìn
1Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA,
ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi.
2Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun,
láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀;
ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta,
ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀.
3Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,
àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa.
Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,
wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.
4Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà,
tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA,
tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn,
àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa.
5OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa,
o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá.
Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ;
bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe,
kí n máa ròyìn wọn,
wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ.
6O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,
ṣugbọn o là mí ní etí;
o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
7Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;
a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:
8mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;
mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”#Heb 10:5-7
9Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.
Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀.
10Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.
Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;
n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
ninu àwùjọ ńlá.
11Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,
sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.
Adura Ìrànlọ́wọ́
12Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,
ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,
tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.
Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
ọkàn mi ti dàrú.
13OLUWA, dákun gbà mi;
yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.
14Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́
gba ẹ̀mí mi,
kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata,
jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,
kí wọ́n sì tẹ́.
15Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n,
kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú,
àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi.
16Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀,
kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ;
kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ
máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!”
17Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí;
ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi,
má pẹ́, Ọlọrun mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 40: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀