ORIN DAFIDI 39

39
Ìráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ
1Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra,
kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀;
n óo kó ẹnu mi ní ìjánu,
níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.”
2Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan;
n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá;
sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i
3ìdààmú dé bá ọkàn mi.
Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú;
mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní:
4“OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi,
ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi,
kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.”
5Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan,
ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ;
dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán.
6Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji,
asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀;
eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá,
láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ.
7Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé?
Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì.
8Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi;
má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀.
9Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi;
nítorí pé ìwọ ni o ṣe é.
10Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi,
mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí.
11Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyà
pẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ.
Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan.
12“OLUWA, gbọ́ adura mi,
tẹ́tí sí igbe mi,
má dágunlá sí ẹkún mi,
nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́;
àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi.
13Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi,
kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ;
àní, kí n tó ṣe aláìsí.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 39: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀