O. Daf 39:1-13
O. Daf 39:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
MO ni, emi o ma kiyesi ọ̀na mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣẹ̀; emi o fi ijanu ko ara mi li ẹnu nigbati enia buburu ba mbẹ niwaju mi. Mo fi idakẹ yadi, mo tilẹ pa ẹnu mi mọ́ kuro li ọ̀rọ rere: ibinujẹ mi si ru soke. Aiya mi gbona ninu mi, nigbati emi nronu, ina ràn: nigbana ni mo fi ahọn mi sọ̀rọ. Oluwa, jẹ ki emi ki o mọ̀ opin mi ati ìwọn ọjọ mi, bi o ti ri; ki emi ki o le mọ̀ ìgbà ti mo ni nihin. Kiyesi i, iwọ ti sọ ọjọ mi dabi ibu atẹlẹwọ; ọjọ ori mi si dabi asan niwaju rẹ: nitõtọ olukuluku enia ninu ijoko rere rẹ̀ asan ni patapata. Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ. Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ. Gbà mi ninu irekọja mi gbogbo: ki o má si sọ mi di ẹni ẹ̀gan awọn enia buburu. Mo yadi, emi kò ya ẹnu mi; nitoripe iwọ li o ṣe e. Mu ọwọ ìna rẹ kuro li ara mi: emi ṣegbe tan nipa ìja ọwọ rẹ. Nigbati iwọ ba fi ibawi kilọ fun enia nitori ẹ̀ṣẹ, iwọ a ṣe ẹwà rẹ̀ a parun bi kòkoro aṣọ: nitõtọ asan li enia gbogbo. Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri. Da mi si, ki emi li agbara, ki emi ki o to lọ kuro nihinyi, ati ki emi ki o to ṣe alaisi.
O. Daf 39:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀; èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.” Mo fi ìdákẹ́ ya odi; mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere; ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i. Àyà mi gbóná ní inú mi. Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn; nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀: “OLúWA, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín. Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ: Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela. “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ. “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, OLúWA, kín ni mo ń dúró dè? Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ. Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo. Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn àwọn ènìyàn búburú. Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́; èmi kò sì ya ẹnu mi, nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é. Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi; èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ. Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà rẹ parun bí kòkòrò aṣọ; nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo. “Gbọ́ àdúrà mi, OLúWA, kí o sì fetí sí igbe mi; kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí. Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára, kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí, àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”
O. Daf 39:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra, kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀; n óo kó ẹnu mi ní ìjánu, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.” Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan; n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá; sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i ìdààmú dé bá ọkàn mi. Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú; mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní: “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi, ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi, kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.” Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan, ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ; dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán. Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji, asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀; eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá, láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ. Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé? Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì. Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi; má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀. Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi; nítorí pé ìwọ ni o ṣe é. Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi, mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí. Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyà pẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ. Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan. “OLUWA, gbọ́ adura mi, tẹ́tí sí igbe mi, má dágunlá sí ẹkún mi, nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́; àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi. Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi, kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ; àní, kí n tó ṣe aláìsí.”