ORIN DAFIDI 39:1-13

ORIN DAFIDI 39:1-13 YCE

Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra, kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀; n óo kó ẹnu mi ní ìjánu, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.” Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan; n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá; sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i ìdààmú dé bá ọkàn mi. Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú; mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní: “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi, ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi, kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.” Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan, ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ; dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán. Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji, asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀; eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá, láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ. Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé? Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì. Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi; má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀. Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi; nítorí pé ìwọ ni o ṣe é. Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi, mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí. Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyà pẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ. Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan. “OLUWA, gbọ́ adura mi, tẹ́tí sí igbe mi, má dágunlá sí ẹkún mi, nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́; àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi. Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi, kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ; àní, kí n tó ṣe aláìsí.”